Ṣodiyan bẹbẹ fun isọkan apapọ fijilante nipinlẹ Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 15 November 2020

Ṣodiyan bẹbẹ fun isọkan apapọ fijilante nipinlẹ Ogun

 


Alakoso fẹgbẹ awọn fijilante, Oloye Sodiyan ti bẹbẹ fun ajọṣepọ isọkan fẹgbẹ awọn alaabo fijilante ni eyi ti yoo mu ki alaafia jọba, ki ọwọ wọn si le tẹ nnkan ti wọn n wa.

O sọrọ yii nibi ipade apapọ fijilante lati di ọkan fun eto abo nipinlẹ Ogun, nibi tawọn aṣoju lati So-Safe Corps, fijilante, awọn ọdẹ atawọn mii-in ti peju pesẹ niluu Abẹokuta.

O sọ pe nnkan ẹyọ kan to jẹ gbogbo awọn to wa nibi ipade naa logun, ni gbogbo wọn yoo ṣe parapọ di ẹyọ kan, ti wọn yoo si maa fimọ sọkan lori ohun gbogbo ti wọn ba n ṣe pẹlu ijọba.

O ni pẹlu bi nnkan ṣi ṣe n lọọ yii, o daju pe ohun gbogbo yoo ja si rere, ti yoo si wulo fun gbogbo mutumuwa. O wa fi akoko naa rọ gbogbo awọn to ba ni ikunsinu lati yanju ẹ, nitori ọmọ iya kan naa ni gbogbo wọn.

Bakan naa ni gbogbo awọn to tun sọrọ lọjọ naa fi idunnu wọn han si ipade ọhun pẹlu ileri pe gbogbo ti gba lati jọ ṣiṣẹ pọ fun eto abo nipinlẹ Ogun.

No comments:

Post a Comment

Pages