Alaaji Akeem Bọdunrin,tọpọ mọ si Iyẹru, to jẹ alaga to n ṣakoso ọrọ garaji nipinlẹ Ogun, ti sọ pe ko si oootọ ninu ahesọ tawọn kan n gbe kaakiri pe wọn ti gbakoso lati maa ja tikẹẹti ni garaji lakooko ọsẹ NURTW lọwọ oun, o ni titi di akoko yii oun loun si n paṣẹ.
O ni " Bi ẹ ṣe ri bayii, a ṣẹṣẹ pari ipade ọlọsọọsẹ wa, ko si si wahala kankan laarin wa ati lawọn garaji pẹlu. Mo wa fi n da gbogbo araalu loju pe ko si awuyewuye kankan laarin wa ati pe emi ni mo ṣi wa nipo ti Gomina Abiọdun fi mi si naa.
Lori ọrọ ta lo gba akoso ọfiisi ẹgbẹ naa, Iyẹru sọ pe oun ko ro pe o yẹ kawọn kọbiara lee lori, eyi to ṣe Pataki to yẹ kawọn maa beere lọwọ ara wọn ni pe ta ni Gomina Dapọ Abiọdun fi jẹ alaga ẹni ti yoo maa ja tikẹẹti lakooko tawọn awakọ ba n ṣiṣẹ.
No comments:
Post a Comment