Gomina Dapọ Abiọdun ti yan ọkan lara ajafẹtọọ, to si tun jẹ ọjẹ agba oniroyin, Ọgbẹni Tunde Ọladunjoye gẹgẹ alaga igbimọ ti yoo maa ṣamojuto ileeṣẹ tẹlifiṣan OGTV,nipinlẹ Ogun
.
Loni in, Ọjọbọ, Tọsidee, ni Gomina yan ọkunrin naa lakooko to darukọ
awọn igbimọ tuntun lawọn ẹka ileeṣẹ nipinlẹ ọhun atawọn oludamọran pataki mẹfa
.
Ọladunjoye to jẹ akowe olupongo fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun lawọn eeyan ti sọ pe o kun oju oṣuwọn ipo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan an si yii ti wọn sọ pe o le mu aṣeyọri ba ileeṣẹ tẹlifiṣan ọhun.
Wọn lawọn iriri ẹ gẹgẹ bi oniroyin yoo tubọ ran an lọwọ
. , .
No comments:
Post a Comment