La.a arọ yii ni Ọgbẹni Ṣẹgun Ṣowumi, olupolongo fun Alaaji Atiku Abubakar, oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun lọ sabẹwo si idile
Oloogbe Buruji Kashamu, niluu Ijẹbu- Igbo, lati bawọn kẹdun akọni wọn
to lọ .
Gẹgẹ bo ṣe wi , o ni oun wa bawọn kẹdun lorukọ Waziri Atiku Abubakar
fun ti ipapoda agba oṣelu nni Sẹnetọ Buruji Kashamu,ẹni to jade laye lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.
O ni ojiji niroyin iku naa wọle tọ wọn wa, ti jinnijinni ẹ si dabo wọn titi di
akoko yii. O ṣapejuwe Kashamu gẹgẹ bi akọni, tawọn ipa to ko le di igbagbe ninu oṣelu.
O ni 'Mo kin yin pele fun ti iku Sẹnetọ Kashamu nnkan nla lo ṣẹlẹ yii, ṣugbọn a dupe lọwọ Ọlọrun fun igbe aye Oloogbe Kashamu, ẹni ti aye si sile. Mo gba ladura pe ki Ọlọrun ọba ko fo ri ji oku. Ki ẹyin wa naa dara. Mo ki yin ni orukọ Waziri Atiku Abubakar pe ẹ ku ara fẹra ku'
O ni gboogbo iṣẹ rere ti ọkunrin naa ṣe laye ko ni parẹ ati pe ẹkọ nla nikuu ọhun jẹ fun gbogbo awọn pe ọjọ kan bayii nikuu yoo pa oju wa de.
No comments:
Post a Comment