Kashamu, Erinlakatabu ti lọ o- Ṣẹgun Ṣowumi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 12 August 2020

Kashamu, Erinlakatabu ti lọ o- Ṣẹgun Ṣowumi

  

Ṣẹgun Sowumi, agbẹnusọ fun Abubakar Atiku lakooko ipolongo aarẹ fẹgbẹ oṣelu PDP, lorileede yii, ti sapejuwe iku Buruji Kashamu, gẹgẹ bi ẹja nla to lọ, erin lakatabu to sun ti ko le dide mọ.

 

Gẹgẹ bi iwe ibanikẹdun to fi sita, o ni nnkan kan to ṣe pataki, to si yẹ ki ọmọ ẹda maa fi sọkan ni pe tiku ba ti mu ẹnikan lọ ko si ogun tabi adura taa fi le daa pada mọ, o nitọhun ti lọ patapata niyẹn.

 

O  ni o jẹ ibanujẹ ati ẹdun kan pe akọni loju ija, onigboya laibẹru ẹnikẹni, aṣaaju nidi oṣelu, Buruji Kashamu faye silẹ lẹni ọdun mejilelọgọta.

 

Ṣowumi ni gẹgẹ bi ọrọ ọkunrin yii nigba to wa laye pe ofo nijọ keji ọja, eyi to ma fi n ṣapejuwe ko si nnkan mi in mọ,tile aye yii b a ti kọja. O ni oun jẹ ẹnikan to sunmọ ọn, toun mọ pe o ni okun, oun mọ gẹgẹ bi alaanu eeyan, pabambari ẹ ni pe oun mọ gẹgẹ bi ẹni to to ṣe ẹgbọn, to si tun jẹ aṣaaju rere.

 

Ṣowumi sọ pe “ Bawo ni mo ṣe fẹẹ tu Ṣẹri atawọn aburo ẹ ninu pe baba wọn ko si mọ. Ẹni to jẹ pe ipasẹ ẹ lọpọ awọn eeyan ti dide, ẹni ti Ọlọrun fi ọpọlọ jinki ẹ, to si mọ nipa awọn nnkan to n ṣe daadaa laiboju wo ẹyin.

 

O ni lọpọ igba ni ọkunrin yii maa n duro ti ọrọ to ba sọ, to ba si fẹẹ yipada yoo jẹ kawọn eeyan mọ pe oun ti kuro ninu ọrọ to n sọ, oun ti yii pada yoo si sọ idi to fi ṣe iru nnkan bẹẹ.

 

Ọkan ninu awọn aṣaaju PDP tun ṣalaye pe Buruji lẹnikan ṣoṣo to duro ti eeyan loju ogun, nigba mii in, o maa n ya awọn eeyan lẹnu pe bawo ni okun ati agbara lati ṣe iru awọn nnkan wọnyii.

 

O loun wa beere lọwọ ara oun pe ki lo de to fi jẹ pe arun koronafairọọsi lo n mu miliọnu ẹmi awọn eeyan lọ paapaa julọ. O wa ṣapejuwe ọkunrin yii gẹgẹ bi akọni to ja ti ko sẹni to bori ẹ ṣugbọn tiku bori ẹ nigbẹyin.

 

Ṣowumi wa fọrọ kuraani pari ọrọ ẹ, to sọ pe gbogbo ọkan aye yii ni yoo tọ iku wo, ti wọn yoo si gba  gba ma-binu, lọjọ ajinde. Ẹni to ba ṣe rere, yoo gba ere ẹ lọjọ naa, ẹni to si ṣe idakeji, ere tiẹ naa n bẹ.

 

O wa ba gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun lapapọ, ọmọ ilẹ Yoruba, ati gbogbo orileede Naijiria kẹdun Ẹṣọ Jinadu Ṣodipẹ  tọpọ mọ si Buruji Kashamu, , o ni ki Ọlọrun foriji, ko si tẹ si afẹfẹ rere.

 

 

No comments:

Post a Comment

Pages