Emi ni iku Buruji Kashamu dun ju,a le ja nipa oṣelu ṣugbọn kii ṣe bi ti iku- Bayọ Dayọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 11 August 2020

Emi ni iku Buruji Kashamu dun ju,a le ja nipa oṣelu ṣugbọn kii ṣe bi ti iku- Bayọ Dayọ

 

 Alaga fẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun tẹlẹ, Oloye Bayọ Dayọ ti sọ pe

loootọ loun ati Oloogbe Buruji Kashamu le ja nipa ti ẹran ara tabi ni ti oṣelu, ṣugbon kii ṣe bi ti iku to mu ọkunrin naa lọ lojiji.

 

Ọkunrin naa sọrọ yii nibi atẹjade kan to fi sita fun ibanikẹdun Oloogbe Sẹnetọ Buruji Kashamu, to ku lojiji. O sọ pe pẹlu ẹdun ọkan loun fi ranṣẹ naa.

 

Bayọ Dayọ sọ pe “ Pẹlu ẹdun ọkan ati irora ni mo fi n kọwe ibanikẹdun si aburo mi, ọrẹ mi, ati alajọṣepọ oloṣelu to tun wa jẹ alaanu mi, iyẹn Buruji Kashamu, lojiji ni iroyin iku ẹ yii de ba mi’’

 

“ Gẹgẹ bi ẹlẹran ara, ko si ki aiyede maa wa, paapaa julọ nipa erongba awa oloṣelu le ma ja jọ bara mu. Ṣugbọn mo sọ pe emi niku ẹ  dun ju, nitori bi mi o ṣe ni anfaani lati bọ ọ lọwọ tabi jọ rẹrin in papọ mọ.”

 

O loun wa gbadura pe ki Ọlọrun foju wo gbogbo aiṣedede ẹ, ko si dari ji I, ki o si tẹ si afẹfẹ rere. Bẹẹ lo lo akoko naa lati ki awọn mọlẹbi, ọrẹ,awọn eeyan ipinlẹ ati ti orileede ku afẹra ku, ọdun yoo jinna si ara wọn.

 

 

No comments:

Post a Comment

Pages