O sọrọ yii lakooko to n gba awọn ọmọ ẹgbẹ onimọ-ẹrọ, ti ẹka ti Abẹokuta lalejo ni ọfiisi ẹ.Abẹwo yii lawọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wa fẹbun awọn ifọwọ igbalode ti Ọgbẹni Ayinla Ahmed ati Omidan Simbiat Ọdẹniyi ṣe ta ipinlẹ Ogun lọrẹ lati fi dena arun koronafairọọsi.
Igbakeji Gomina ṣalaye pe gbogbo wa la mọ pe aisan tan kalẹ awọn igberiko nipa fi fọwọ kan oju ati imu ati ọwọ awọn to lugbadi aisan ọhun, idi niyi to ni a gbọdọ gbe awọn igbesẹ lati fopin si, lakooko to jẹ pe nnkan ti n pada bọ sipo, tawọn ile-ẹkọ ti n wọle, tawọn ile-ijọsin naa si ti n mura lati bẹrẹ iṣẹ isin wọn.
O wa gboriyin fẹgbẹ awọn onimọ-ẹrọ lori bi wọn ṣe ṣe ẹrọ ifọwọ igbalode eyi to sọ pe yoo wulo fawọn eeyan, o wa ni ipenija leyi jẹ fawọn fawọn ileeṣẹ to n gbe awọn nnkan jade lati ṣagbekalẹ iru nnkan bẹẹ lati fi dena koronafairọọsi yii.
Ko to to akoko yii ni alaga fẹgbẹ awọn onimọ-ẹrọ naa, Lanre Apampa, ti gboriyin fun ijọba ipinlẹ Ogun lori bi wọn ṣe tete gbe igbesẹ lori ọrọ koronafairọọsi, o ni lakooko konile-o- gbele yii, ẹgbẹ yii fatilẹyin wọn han nipa fi fun ijọba ni miliọnu kan naira.
Ninu iroyin mii in ẹwẹ, ẹgbẹ to n ri si isakoso ọrọ iṣẹ iyẹn, Nigerian Directorate of Employment,NDE, fi ibomu ẹgbẹrun meji tawọn to n kọṣẹ labẹ wọn ni Sabo, niluu Abeokuta tọrẹ.
Nigba to n ko awọn ẹbun naa kalẹ, Dokita Nasir Ladan , alakoso agba fajọ naa ti Bamgbade Adekunle, alakoso wọn nipinlẹ Ogun soju fun sọ pe awọn ṣe eleyii lati fi iranlọwọ wọn han si ijọba, lati le fopin si itankalẹ arun to n ja kaakiri.
No comments:
Post a Comment