Alakoso fajọ fijilante nipinlẹ Ogun, Ṣọla Ṣodiyan, ti ṣedaro iku agba oṣelu nni, Sẹnẹtọ Buruji Kashamu, gẹgẹ bi eyi ti ko yẹ ko waye lakooko yii, nitori awọn ipa ribiribi tọkunrin naa ko.
O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ nibi isinku agba oloṣelu ọhun to waye lọsan oni niluu Ijẹbu-Igbo. O ni ko sẹni to gbọ nipa iku ojiji to pa oju ọkunrin naa de, ti ko ṣe nii kayefi.
O ni oun mọ pe ko sẹni to le di Ọlọrun lọwọ nigba to ba n ṣiṣẹ ẹ, nitori oun lo ni ẹmi gbogbo wa. O ni akọni lọkunrin naa nigba to wa laye to si tun jẹ ẹlẹyinju aanu, o wa gbadura pe ki Ọlọrun fori ji, ko si tu awọn ẹbi ẹ ninu.
No comments:
Post a Comment