Alakoso fajọ fijilante nipinlẹ Ogun, Ṣọla Ṣodiyan ti rọ gbogbo awọn to n sọrọ si ọga agba fijilante nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Nureni Adedoyin lati jawọ, ki wọn si ṣe suuru, nitori akoko iṣọkan lawọn wa bayii ki i ṣe lati maa fi ọrọ tun da wahala silẹ.
O sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita, o ni akoko tawọn wa yii ki i ṣe lati ma foko ọrọ ranṣẹ si ara wọn bi ko ṣe lati wa ọna bi isọkan tawọn n gbero ẹ yoo ṣe waye, ti alaafia yoo si jọba.
O ni gẹgẹ bi oun ko sẹni to n baja ninu ajọ naa, nitori iṣẹ to wa niwaju oun ju gbogbo ẹ lọ, oun ko si fẹ ki Adedoyin atawọn kan ma fọrọ buruku ranṣẹ si ara wọn, nitori ko bojumu.
O wa rọ gbogbo awọn tọrọ lati fi ba nnkan jẹ ba n gbe ninu ki wọn ṣe suuru, ki wọn si maa wa ọna ti ilọsiwaju yoo fi de ba ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, nitori bi ko ba si isọkan, inu ijọba ko le dun sawọn ati pe wọn ko ni le ṣatilẹyin to yẹ fawọn.
Ṣodiyan wa pari ọrọ ẹ pe oun ko fẹ kawọn tun gbe igbekugbe jade lori Adedoyin, tabi koun naa gbe nnkan to le da wahala silẹ jade, nitori igbega ipinlẹ Ogun, ajọṣe gbogbo wọn ni.
No comments:
Post a Comment