Ọnarebu Olufunmilayọ Irede ranṣẹ ibanikẹdun lori iku Buruji Kashamu - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 9 August 2020

Ọnarebu Olufunmilayọ Irede ranṣẹ ibanikẹdun lori iku Buruji Kashamu

 

 

Arabinrin Ọnarebu Olufunmilayọ Irede Ọginni, to jẹ ọkan lara awọn oloṣelu nipinlẹ Ogun, ti ranṣẹ ibanikẹdun lori iku Sẹnetọ Buruji Kashamu, ẹni to jade lanaa, ọjọ Abamẹta, Ṣatide.

Ninu atẹjade kan to fi sọwọ si wa, lo ti ṣapejuwe iku agba oloṣelu ọhun gẹgẹ bi adanu nla, ati pe awọn ipa ẹ lori oṣelu, ko nii parẹ titi lai. O sọ pe iku ojiji to pa ọkunrin yii si n jẹ kayefi foun latigba toun ti gbọ.

Obinrin yii wa ṣapejuwe Buruji gẹgẹ bi ẹni ti Ọlọrun fun lọgbọn ati oye, o ni gbogbo igba toun fi sunmọ ọn nigba to wa laye, loun fi ri ọgbọn kọ lara ẹ, nitori ẹni to ko ara ẹ nijanu ni, ti ko si faye gba iwa ẹgbin.

O tun ṣalaye pe ẹlẹyinju aanu ni ọkunrin ọhun ti ko fọrọ awọn mẹkunnu ṣere, o wa gbadura pe ki Ọlọrun fọrun kẹ, ko si tẹ ẹ si afẹfẹ rere. Ko si dari gbogbo aiṣedeede ẹ ji.

No comments:

Post a Comment

Pages