Apapọ di ẹyọ kan ninu ẹgbẹ fijilante yoo fopin si imọtara ẹni-nikan- Ọṣifẹsọ Abiọdun Chris - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 9 August 2020

Apapọ di ẹyọ kan ninu ẹgbẹ fijilante yoo fopin si imọtara ẹni-nikan- Ọṣifẹsọ Abiọdun Chris

 

 

Ọgbẹni Ọṣifẹsọ Abiọdun Chris ti sọ pe apapọ isọkan ajọ alaabo fijilante nipinlẹ Ogun, ti Ọgbẹni Ṣọla Ṣodiyan, to jẹ alakoso ajọ naa n ṣe jẹ itẹwọgba gbogbo ẹgbẹ naa, ko si sẹni ti ko fọwọ si, ki iru nnkan bẹẹ ṣẹlẹ, nitori yoo yọ wọn kuro oko ẹru ati imọtara ẹni nikan awọn ti ko fẹẹ ki iṣọkan waye ninu ajọ yii.

Ọkunrin yii sọrọ ọhun ninu atẹjade to fi sita lati tako ọrọ ti Nureni Adedoyin,Ọlawale ati Ẹnitan sọ lori ki ẹgbẹ naa di ọkan, eyi ti wọn sọ pe awọn ko mọ nnkankan nipa ẹ. O ni awọn ti ko ba fẹẹ ki ilọsiwaju ba ẹgbẹ fijilante lo le ni iru awọn ero buruku bẹẹ lọkan.

O sọ pe fijilante jẹ eyi ti wọn da silẹ, ti wọn si forukọ ẹ silẹ labẹ Corporate Affairs Commission, iyẹn [CAC] pẹlu nọnmba RC:11834, lọjọ kẹrin, oṣu kẹta ọdun 2003, lati maa pese abo fẹmii ati dukia awọn eeyan lawujọ.

Ati lati maa gbogun ti awọn iwa ọdaran labẹ bo ti wu, ko ri lorileede yii. O ni bo tilẹ jẹ pe wahala wa laaarin awọn ọmọ ẹgbẹ ọkan si ekeji lati ti da ẹgbẹ naa ru, ti wọn si foko ọrọ ranṣẹ si ara wọn loorekoore ti wọn si figagbaga lati mọ eyi to jẹ ọga laaarin wọn.

O ni pẹlu gbogbo nnkan wọnyii, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ni Abuja ṣi fawọn fijilante ti wọn si n reti ki Aarẹ orileede yii buwọ lu iwe ofin, eyi ti wọn ti gba wọle lati ọdun 2014. O ni o yẹ ki wọn gboriyin fun Ṣodiyan, ọmọ bibi ilu Ikenne fawọn akitiyan ẹ fun ẹmi ọgbọn to n lo lati koju awọn ipenija ẹgbẹ naa.

O ni Alaaji Ali Ṣokoto diidi pe si Kaduna lati jọ fikun lunkun pẹlu awọn ti Mohammed Jahun lati wa abayọ si wahala to n waye ninu ajọ fijilante, ki wọn si di ọkan,ki ohun gbogbo le pada bọ sipo, bi wọn ṣe lero ẹ tẹlẹ.

Ọsifẹsọ tun ṣalaye ninu atẹjade ẹ pe  lakooko yii ti ọrọ ki fijilante di ọkan ṣoṣo jade, to si jẹ akoko ti Amọtẹkun naa balẹ silẹ Yoruba, gbogbo awọn ajọ tọrọ naa kan nipinlẹ Ogun, pe ara wọn pọ lati fimọsọkan fun ilọsiwaju ẹgbẹ alaabo Amọtẹkun nipinlẹ naa, awọn naa ni fijilante So Safe Corps, atawọn ọdẹ.

O ni o yẹ ki Adedoyin Olanrewaju Nureni, mọ awọn nnkan to yẹ ko maa sọ, nitori bi ẹni pe oun lọga gbogbo eeyan lo fi maa n sọrọ  ti ko mu itumọ dani lati fi ba awọn nnkan ti wọn ba ti to jẹ. O ni ọpọ igba lo ti maa huwa igberaga pẹlu awọn oloye ẹgbẹ naa lapapọ, to ro pe oun dari  oun nikan loun le dari fijilante ti M.Jahun ati pe ko sẹni to le yẹ oun lọwọ wo.

Ọkunrin yii tun sọ pe Adedoyin yii kan naa lo paṣẹ pe kawọn ọmọ ẹyin ẹ lu oun laduugbo Broad ni Adigbe, ti wọn si ja oun si ihoho, ti gbogbo ara oun si bẹjẹ.O ni nigba ti ko tẹ ẹ lọrun, lo gbero lati pa oun, to ni ki wọn fi mamu gari soun lọwọ, ti wọn si gbe oun lọ si teṣan Adgbẹ, ti wọn si da oun duro fọjọ kan, ko to di pe oun rẹni gba oun silẹ..

O ni Adedoyin  yii na lo fun Ṣodiyan niwe ifẹsun kan lọjọ kejidiinlogun, oṣu keje, ọdun 2018, lati dahun sawọn ẹsun ti wọn ṣagbekalẹ ẹ lati fi ba orukọ rere ti ọkunrin naa ni jẹ. O wa pari ọrọ ẹ pe igbesẹ ti Ṣodiyan gbe lati sọ fijilante di ọkan jẹ itẹwọgba ko si sẹni to le daa duro

No comments:

Post a Comment

Pages