Lẹta ibanikẹdun ni Ọbasanjọ kọ, ṣugbọn oko ọrọ lo fi ranṣẹ si Buruji Kashamu lọrun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 9 August 2020

Lẹta ibanikẹdun ni Ọbasanjọ kọ, ṣugbọn oko ọrọ lo fi ranṣẹ si Buruji Kashamu lọrun.

 

 

Gbogbo awọn to ri lẹta ibanikẹdun ti Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ fi ranṣẹ si Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun, lori iku Sẹnetọ Buruji Kashamu, to jade laye lọjọ Abamẹta, Satide, ana, lo n ṣe ni kayefi pe iru lẹta wo leleyii.

Lọsan ana, ti iroyin iku agba oloṣelu ninu ẹgbẹ oṣelu PDP gba igboro kan, ni Oloye Oluṣegun Ọbasanjọ tí fi lẹta ibanikẹdun ranṣẹ si Gomina Dapọ, ibanikẹdun lo pe e ṣugbọn oko ọrọ lo pọ nibẹ, ti ẹkọ nla lo yẹ ki iku Kashamu jẹ fawọn alagbara nile aye, ti wọn ni agbara lori aye amọ ti wọn ko ni lori iku.

O ni pẹlu agbara ti Ẹṣọ Jinadu to n jẹ Buruji Kashamu lo laye nipa oṣelu to n lo ofin lati bọ lọwọ awọn iwa buruku to hu lorileede yii ati oke-okun.

Ṣugbọn o ya oun lẹnu pe ko le lo iru awọn nnkan bẹẹ lati da iku duro, lati muu lọ nigba ti ẹni to da gbogbo aye sọ pe akoko ti to fun un lati ṣiro iṣẹ.

O wa ba Gomina Dapọ Abiọdun ati ẹbi agba oṣelu naa kẹdun pẹlu adura pe ki Ọlọrun fọrun kẹ, ko si foju fo gbogbo aisedede ẹ.

 

 

No comments:

Post a Comment

Pages