Sunday Ọlapọsi Ọginni, to jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu New Nigeria People Party, NNPP ati alaga fẹgbẹ apapọ awọn oloṣelu nipinlẹ Ogun, ti ṣapejuwe iku Buruji Kashamu, gẹgẹ bi adanu nla lagbo oṣelu lorileede yii.
Ninu atẹjade kan ti alaga ọhun fi sita lalẹ ọjọ Abamẹta, lo ti sọ pe ẹdun ọkan niku agba oloṣelu yii jẹ foun nigba to n gbọ, o ni aye ti ọkunrin naa fi silẹ lagbara ati pe ẹgbẹ oṣelu ipinlẹ Ogun ko ni ri bakan naa mọ.
O wa ba gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP atawọn ẹbi ọkunrin yii kẹdun adanu nla to ṣẹlẹ yii. O wa gbadura pe ki Ọlọrun fọrun kẹ, ko si foju wo gbogbo aṣiṣe ẹ nu.
No comments:
Post a Comment