Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko ti wọn ṣepade pọ pẹlu awọn igbimọ oloye ẹgbẹ ọhun lapapọ,eyi wọn pe ni NWC, lọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, niluu Abuja.
O sọ pe gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ yii nipinlẹ Ogun lawọn ti gba lati gbagbe gbogbo wahala to ti waye ninu ẹgbẹ ọhun, ti wọn si gba lati jọ ṣiṣẹ pọ
O sọ pe idi pataki tawọn fi wa ni lati wa dupẹ lọwọ wọn fawọn atilẹyin ti wọn ti n ṣe fawọn nipinlẹ Ogun, o ni gbogbo awọn eeyan gidi ilu naa lawọn wa ṣoju fun tawọn si wa fi ẹmi imoore han.
Ogundele sọ pe bi nnkan ṣe ri bayii, oun le fi gbogbo ẹnu sọ pe ko si wahala kankan mọ ninu ẹgbẹ ohun, bi ogo ẹgbẹ naa yoo ṣe pada bọ sipo lawọn jọ n forikori ṣe, to si da oun loju pe didun ni ọsan yoo so.
O gboriyin fun alaga ẹgbẹ naa lapapọ fun ẹmi ọgbọn ti Ọlorun fi jinki ẹ lati maa dari ẹgbẹ naa, o wa gbadura pe Ọlọrun yoo tubọ maa lọra ẹmi ẹ .
Ninu ọrọ Secondus, o rọ gbogbo awọn ipinlẹ yooku lati ya ninu ọgbọn tawọn tipinlẹ Ogun lo, lati yanju aawọ to wa laarin wọn. Lara awọn to wa nibẹ ni Ọmọọba Doyin Okupe, Onimọ-ẹrọ Bayọ Dayọ to ti figba kan jẹ alaga ẹgbẹ naa.Nibẹ ni wọn ti dupẹ lọwọ alaga naa tẹlẹ fawọn ipa to ko lati le jẹ ki isọkan pada sinu ẹgbẹ PDP ipinlẹ Ogun.
No comments:
Post a Comment