Ẹgbẹ ohùn fijilante nipinlẹ Ogun tun ti tan imọlẹ si bi ijọba ipinlẹ Ogun ṣe le Ọgbẹni Nureni Ọlanrewaju Adedoyin kuro ninu ajọ fijilante nipinlẹ Ogun, lakooko to jẹ igbakeji ọga agba fun ileeṣẹ naa.
Ninu lẹta ti wọn fi sọwọ si wa ni wọn ti ṣalaye pe
ọkunrin ọhun ko ṣẹṣẹ bẹrẹ agabagebe iwa to hu, wọn lo ti wa lẹnu ẹ tipẹ.Wọn ni
lakooko naa Ṣọji Ganzallo, ni ọga ẹ,
toun si jẹ igbakeji ẹ.
Ṣugbọn awọn iwakiwa ọwọ ẹ lati maa jẹ ọga ẹ lẹsẹ atawọn
iwa mii in njjọba ri lọwọ ẹ ti wọn fi fun un ni lẹta gbele ẹ lọjọ kẹjọ, oṣu
kọkanla,ọdun 2016.
Eyi ti akọle lẹta da lori Ijọba ipinlẹ Ogun yọ igbakeji ọga agba fijilante. Ohun to ka
bayii “ Ijọba ipinlẹ Ogun ti kede yiyọ Ọgbẹni Adedoyin Ọlanrewaju, to jẹ
igbakeji ọga agba fajọ fijilante nipinlẹ naa danu.
“Gẹgẹ bi atẹjade ti akọwe agba fun ileeṣẹ to n ri si ọrọ
oye jijẹ ati ijọba ibilẹ,Ọgbẹni Abayọmi Ṣobande fọwọ si nigba naa, Wọn ni wọn
yọ ọkunrin ọhun lori awọn iwa ọkanọjọkan to hu.
Lati fi gbe lẹta ọhun lẹyin nigba naa, wọn ni loju ni wọn
ti yọ nipo ọhun. Ṣugbọn pẹlu iwa ainitiju, to si n wa ipo tipatipa lo fi lọ
lẹdi apo pọ mọ awọn Jahun, nibi ti wọn ti fun un ọga agba fijilante, to si n lo
ipo naa lati dabaru awọn alaabo fijilante.
Ẹgbẹ ohùn fijilante wa sọ pe ọpẹlọpẹ Ṣodiyan to jẹ
alakoso ẹgbẹ naa lo lo ore-ofẹ to ni lati fi sun mọ Gomina Dapọ Abiọdun. Eyi to
ni ki gbogbo awọn di ọkan.
Wọn nitori o fẹẹ
fi tpatipa di ọga agba fijilante fun iṣọkan ẹgbẹ naa ti ko raye ẹ lo ṣe tun pada
sẹyin, to wa sọ Ọlawale ati Ẹnitan di ohun elo lati fi ba ẹgbẹ jẹ.
No comments:
Post a Comment