Ẹgbẹ ohùn
fijilante ti sọ pe iwa atoko wa bale jẹ ni Ọlanrewaju Nureni Adedoyin, to jẹ
ọga agba fajọ fijilante nipinlẹ Ogun ati Ọlawale Oluṣọla Jimọh n hu ninu ẹgbẹ fijilante,
nitori awọn iwa idojuti ti wọn hu latilẹ wa.
Ninu atẹjade tẹgbẹ naa fi sita
laaarọ yii ni wọn ti sọ pe eyi tawọn mejeeji ba orukọ ẹgbẹ fijilante nipinlẹ
Ogun ti to gẹ, ki wọn pada siluu wọn.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, wọn ni ọmọ Ibadan pọnbele ni Adedoyin ṣugbọn to
maa n parọ pe oun tan mọ wọn ni Owu, l’Abẹokuta nigba ti Ọlawale ṣi wa lati
ipinlẹ Ọṣun.
Wọn o ṣe pataki
lati gba atẹjade yii sita lati ran awọn ọmọ ipinlẹ Ogun leti lori bijọba ipinlẹ
naa ṣe le Nureni Adedoyin lati ma ṣe kopa ninu awọn nnkan to ba jẹ mọ abo
nipinlẹ ọhun lẹyin ti wọn ti lee danu ninu ẹgbẹ fijilante nipinlẹ Ogun.
Ki ọrọ wọn le
ni ẹri ni wọn ṣe fi ẹda lẹta naa sita fawọn eeyan lati ri.Wọn ni ohun iyalẹnu
lo jẹ pe ṣe ni ọkunrin yii n lo fijilante lati maa fi daabo bo iṣẹ ara ẹ to n
ṣe.
Ẹgbẹ ohùn
fijilante tun fikun ọrọ wọn pe Extreme
Security Services Ltd. lorukọ ileeṣẹ abo ti Adedoyin da silẹ laibofinmu, tawọn
si ti ṣetan lati tu gbogbo ibi ti wọn ti n ṣiṣẹ naa fun ajọ alaabo sifu, nigba
ti akoko ba to.
Oun nikan yii
naa ni wọn sọ pe oun fi gbogbo igba bawọn ọmọ ẹgbẹ fijilante ja nita gbangba,
to si n ko wahala ti nitumọ ba ẹgbẹ fijilante nipinlẹ Ogun, ti kii fẹẹ ri awọn
eeyan Ali Sokoto atawọn alaabo ijọba
ipinlẹ Ogun iyẹn SO-SAFE Corps, ti Ṣọji Ganzallo, jẹ ọga wọn soju.
Awọn ẹgbẹ naa fikun ọrọ wọn pe awọn
ibajẹ ti Adedoyin ti ṣe ninu fijilante ni Ṣọla Ṣodiyan n wa ọna lati ṣe atunṣe
lee lori ni ọga agba fijilante yii ko fẹẹ nitori imọtara ẹni-nikan to n ba a
ja.
Wọn ni bi kii ba ṣe ọpẹlọpẹ Ṣodiyan ni
Gomina Dapọ Abiọdun ko ba ti fofinde ẹgbẹ fijilante nipinlẹ Ogun, lẹyin to ti
sọ fawọn ọba alaye lati ma ṣe ni nnkan papọ pẹlu awọn mọ.
Ko si si nnkan
mii in, wọn ni iwa Adedoyin yii naa ni to maa polongo lori redio, tẹlifisan
lati ma fi ṣi awọn araalu lọkan nipa fijilante. Wọn ni nipaṣẹ ki awọn di ọkan,
Ṣodiyan yii ni wọ sọ pe o wa ọna lati pe awọn ti wọn ti n binu pada, to si mu
isọkan waye laaarin awọn igun mejeeji, iyẹn ti Usman Jahun ati Ali Ṣokoto, ki
ogo ẹgbẹ ọhun le pada si bo ṣe wa.
Wọn lo ṣe awọn laaanu bi Ọlawale ati Ẹnitan ko ṣe gbọn,
nitori bi wọn ṣe gba ki Adedoyin sọ wọn di ohun elo, to n gba wọn kaakiri. Wọn
wa ni akoko ti to fun ọga agba fijilante yii lati dẹkun lati maa da wahala silẹ
ninu ẹgbẹ, nitori iṣọkan lati di ọkan ti Ṣodiyan da silẹ, ajọmọ gbogbo wọn
ni.Lẹta ti wọn ni fi le tijọba ipinlẹ Ogun fi Adedoyin ti wọn fi sọwọ niyii.
No comments:
Post a Comment