Mẹta ninu awọn marun-un to fipa ba obinrin kan sun ni Ogijo ti ha o - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 29 July 2020

Mẹta ninu awọn marun-un to fipa ba obinrin kan sun ni Ogijo ti ha o
Mẹta ninu awọn marun-un ti wọn fẹsun kan pe wọn ba obinrin kan ti wọn foruko bo laṣiiri la gbọ pe wọn ti wa ni teṣan awọn ọlọpaa, nibi ti wọn ti ka boroboro.

Awọn tọwọ tẹ naa ni Ṣọla Ọlaoluwa, Ibrahim Kẹhinde ati Lukman Banjoko.Lọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja lọhun, ni wọn sọ pe awọn eeyan yii huwa naa.

Gẹgẹ bi atẹjade tawọn ọlọpaa fi sọwọ ni wọn ti sọọ di mimọ pe obinrin ti wọn fi tipa ba sun lo lọ fẹjọ sin ni teṣan awọn ọlọpaa to wa ni Ogijo. Obinrin ọhun ṣalaye pe oun pade ẹnikan ti wọn n pe ni “Enny Money” to sọ pe koun daunloodu kinni kan lori foonu pe gbogbo awọn to wa nibẹ ni wọn yoo ran-an lọwọ.
O ni lẹyin toun ṣee tan ni ọkunrin to pe ara ẹ ni “Enny Money’’ bẹrẹ si nii maa n ba oun takurọsọ lori foonu, to si ni koun wa ki oun ni laduugbo Idimogun ni Ogijo. Bo ṣe debẹ lo ni awọn marun-un ko na sii labẹ, I miliọnu lo ni awọn eeyan yii pe ara wọn.
O ni pẹlu tipa ni wọn fi ba oun sun, nigba ti wọn yọ ibọn soun, nigba ti ọkan ninu wọn tun n ya fidio bi wọn ṣe n ba oun sun. Awọn ọlọpaa tun sọ pe bi obinrin naa ṣe wa fẹjọ sun lawọn ti gbe igbesẹ. Ni nnkan bii aago marun-un idaji ọjọ Ẹti, Furaidee, lọwọ wọn tẹ Ṣọla Ọlaoluwa ati Ibrahim Kẹhinde.
Ipasẹ awọn mejeeji yii ni wọn sọ pe ọwọ fi tẹ Lukman Banjoko lọjọ Abamẹta, Satide. Wọn ko gba awọn ọlọpaa lakooko ti wọn fi jẹwọ pe loootọ lawọn n ṣiṣẹ ibi ọhun ati pe obinrin yii lẹnikeji tawọn wu iru iwa yii si
Ileeṣẹ ọlọpaa naa ṣalaye pe ibọn onike ti wọn fi maa n halẹ ati foonu ti wọn fi n ya aworan lawọn ti gba lọwọ wọn gẹgẹ bi ẹri. Ni bayii, Edward Ajogun, to jẹ kọmisanna awọn ọlọpaa nipinlẹ naa ti wa paṣẹ pe ki wọn ko awọn tọwọ si tẹ naa wa si Eleweran, niluu Abẹokuta nibi ti iwadii yoo ti tẹsiwaju.

No comments:

Post a Comment

Pages