Gomina Dapọ Abiọdun ti paṣẹ
pe gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ogun ati labẹ ofin to foun laaye lati ṣofin, ẹnikẹni
nipinlẹ naa ọhun ti ko ba lo ibomu tọwọ ba tẹ yoo fẹwọn oṣu mẹfa gbara.
Lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ nirọlẹ ọjọruu Wẹsidee, lo ti sọ pe ijọba
ko nii foju aanu wo ẹnikẹni to ba tapa si ofin ibomu lawujọ lati dena arun
korona fairọọsi to gbode lati bi oṣu
meloo kan ṣẹyin.
Bakan naa lo tun sọ pe ko
ni saaye fun ariya tabi kiko eeyan jọ lakooko ọdun ileya ti yoo waye lọjọ Ẹti,
Furaidee, to n bọ yii fawọn ẹlẹsin musulumi.
O ni ko si nnkan to n jẹ
yidi lọjọ naa gẹgẹ bi ilana ati abayọri pẹlu ajọ musulumi to ga ju lọ iyẹn Nigerian
Supreme Council for Islamic Affairs (NSCIA).
O wa rọ gbogbo awọn musulumi lati rii pe wọn ṣe ọdun naa
nile wọn, ki wọn si rii pe wọn pa ofin ati ilana arun korona mọ lọjọ naa. Gomina
ni bi wọn ṣe itunu awẹ gẹlẹ ni ki wọn ṣe ti ileya naa.
Nigba to n sọrọ nipa iwọle awọn ọmọleewe,Dapọ Abiọdun, sọ
pe lọjọ kẹrin, oṣu to n bọ yii ni kawọn to wa ni ikangun aṣekagba iyẹn SS3 wọle
fun imurasilẹ idanwo aṣekagba wọn ti wọn fẹẹ ṣe.
Ọsẹ meji gbako lo ni awọn ọmọleewe ọhun yoo fi ṣagbeyẹwo
awọn ẹkọ wọn ko to di pe wọn yoo bẹrẹ idanwo aṣekagba,oniwe mẹwaa, iyẹn WAEC,
lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun yii.
Bakan naa lo ni bi nnkan ba lọ bawọn ṣe fẹ tawọn ile ijọsin si ti gbe awọn igbesẹ tawọn la kalẹ fun wọn, to ba di ọjọ kẹrinla, oṣu to n bọ ni wọn yoo ṣi wọn, ti wọn yoo si pada lọ maa jọsin wọn.
Amọ ṣa, Gomina Dapọ Abiọdun ni ko to digba naa ki nnkan
ṣi maa lọ bo ṣe wa tẹlẹ, nipa pe wọn yoo ṣiṣẹ laaarin ọjọ Aje, Monde si
Furaidee, nigba ti igbele yoo waye lọjọ Abamẹta ati ọjọ Aiku.
Bẹẹ lo ni kawọn ile igbafẹ ṣi wa ni titi pa nigba ti igbele laaarin ago
mẹwaa alẹ si mẹrin si n tẹsiwaju. O wa dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun lori
bi wọn ṣe fọwọsowọpọ lati dẹkun arun korona fairọọsi ọhun.
|
No comments:
Post a Comment