Awọn marun-un kan, ti Babalawo wa ninu wọn, lọwọ awọn ọlọpaa to wa ni Ọdẹda, nipinlẹ Ogun, ti tẹ lori ẹsun idigunjale. Awọn eeyan naa ni Dayọ Ajala, ti inagijẹ n jẹ Otege, ẹni ọdun mọkandinlogiji, Ismaila Badmus, ti inagijẹ ẹ n jẹ Ọbasanjọ, toun jẹ ẹni ọdun marundinlogoji, Joseph Sunday, J J ni wọn pe inagijẹ tiẹ, ẹni ọdun mẹrinlelogun ni wọn pe oun.
Awọn yooku ni Chuckwuemeka Paul, inagijẹ toun ni Ejima, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn
loun tiẹ ati Babalawo wọn, Okikiọla Adeṣina, ẹni ọdun mẹrindinlaadọta.
Ninu atẹjade tawọn ọlọpaa
fi sita ni wọn ti ṣalaye pe ọwọ awọn digboluja ọlọpaa tẹ awọn eeyan yii lori ẹsun
pe ogbologbo adigunjale ni wọn ti wọn yọ awọn ara agbegbe Oṣiẹlẹ lẹnu.
Wọn ni bi wọn ṣe ta awọn ọlọpaa
lolobo ni ọga wọn ni agbegbe naa CSP Tijani
Muhammed, ti ṣaaju awọn yooku ẹ lati wa awọn afurasi ọhun jade nibi ti wọn wa,
ti wọn si ri mẹrin mu ninu wọn.
Bi wọn ṣe mu wọn ni wọn ti jẹwọọ pe awọn babalawo to jẹ Baba isalẹ fawọn to maa n ṣoogun tawọn n lo tawọn ba fẹẹ lọ jale to si tun maa n ṣebura fawọn to ba ṣẹṣẹ darapọ mọ wọn.
Loju ẹsẹ lawọn ọlọpaa lọ
mu Okikiọla, lara awọn nnkan ti wọn ri gba lọwọ wọn ni Ibọn, aake, “ọbẹ meji, atawọn nnkan oloro mii in.
Ni
bayii, kọmiṣanna awọn ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Edward A. Ajogun, ti wa paṣẹ pe ki wọn
bẹrẹ iwadii lori iṣẹ ibi tawọn afurasi tọwọ ti ba naa ti ṣe, ki wọn si foju
bale-ẹjọ laipẹ.
No comments:
Post a Comment