Onimọ-ẹrọ Olugbenga Olugbile, to jẹ alaga fifihẹ iyẹn kiatika nijọba ibilẹ Ijẹbu-Ode ti gboriyin fun Gomina Dapọ Abiọdun lo bo ṣe ṣe idasilẹ ileesẹ to yoo maa ri si igboke-gbodo nipinlẹ Ogun, o ni igbesẹ nla ni.
O sọrọ yii
lakooko to n bawọn oniroyin nigba to tẹle Onimọ-ẹrọ Gbenga Dairo to jẹ
kọmissanna feto igboke-gbodo nipinlẹ Ogun, fun abẹwo ẹ si garaaji Eko,ọkan lara
ibudokọ to wa niluu Ijẹbu-Ode.
O fi iduunu ẹ
han lori igbesẹ akọ to ni Gomina gbe naa ati bo ṣe fi ẹni to mọ nipa tifun-tẹdo
ileesẹ naa lati maa ṣakoṣo ẹ . O ni o da oun loju pe ileesẹ igboke-gbodo naa
yoo tun jẹ anfaani lati le jẹ kawọn ijọba ibilẹ dun un wo ti yoo si tun pese
awọn ohun amayedẹrun ti idagbasoke yoo si tun de ba awọn ọna gbogbo.
Ko to to akoko naa ni kọmisanna fọrọ
igbokegbodo Gbenga Dairo ti sọ ninu ọrọ ẹ pe lara erogba ijọba lati mu
idagbasoke ba ipinlẹ yii lori awọn ọna gbogbo lo mu koun ṣabẹwo sawọn ijọba
ibilẹ lati mọ iṣoro ti wọn n koju ati lati wa ọna abayọ si.
O ni gbogbo ọna ni ijọba n fi ṣiṣẹ
lati le ri pe irọrun de ba igboke-gbodo araalu.
Nipa pipese awọn ọna to ja gaara fawọn araalu. Bẹẹ tun ni kọmisanna ọhun tun lo anfaani yii lati ba ẹgbẹ awọn onimọto sọrọ ni garaaji, to si gba wọn lamọran lori ati deena arun korona fairọọsi to n ja lode bayii.
Onimọ-ẹrọ Dairo tun ti kọkọ ṣepade
pọ pẹlu alaga kiatika Ijẹbu-Ode naa Olugbenga Olugbile, olori isakoso nijọba ibilẹ
naa, Dokita Adeolu Olufowobi ati alakoso fọrọ iṣẹ Olufiṣan Oṣiyale.
No comments:
Post a Comment