Oloye Ṣọla Ṣodiyan, ọkan lara awọn
alakoso fajọ alaabo fijilante nipinlẹ Ogun ti ṣapejuwe Nureni Adedoyin, Olusọla
Ọlawale atawọn eeyan wọn kan gẹgẹ ni agba ofifo lasan, ti wọn kan fẹẹ maa tori
fijilante polongo ara wọn lori awọn oriṣiriṣi irọ ti wọn n gbe jade.
Ọkunrin naa sọrọ yii ninu atẹjade to
gbe jade lori awọn ẹsun ti wọn ni ko nitumọ ti wọn ni Oluṣọla Ọlawale gbe jade
pẹlu ati lẹyinNureni Adedoyin, ti wọn pe ni ọga agba awọn fijilante nipinlẹ
Ogun.
O ni ko si bi nnkan ṣe n lọ ti
Nureni Adedoyin ko mọ nipa ẹ ṣugbon nigba to fẹẹ ki iwa imọtara-ẹni bọ lo muu fa
sẹyin. Ọkunrin naa sọ pe iyalẹnu lo jẹ foun nigba toun ka bi wọn ṣe bu oun, O
ni ko so tun jẹ iyalẹnu foun lọna keji nitori wọn ti kilọ foun tẹlẹ lati ma bawọn
wọn ni nnkankan papọ tẹlẹ nitori awọn iwa agabagebe to wa lọwọ wọn.
Ṣodiyan ṣalaye
pe igbagbọ toun ni pe to ba jẹ pe loootọ eto abo awọn eeyan atawọn araalu lo jẹ
wọn logun gẹgẹ bi erongba toun o yẹ kawọn jọ wa ni iṣọkan, ki wọn si jọ maa
ṣiṣẹ papọ.
O ni “ Nnkan to dun mi ni bi wọn ṣe
parọ pe awọn ko mọ nipa bi wọn ṣe fẹẹ ṣiṣẹ papọ gẹgẹ bi alaabo to nii ṣe pẹlu
fujilante,So-Safe Corps atawọn alaabo yooku, wọn mọ nipa ẹ daadaa nitori funra Adedoyin
lo gba lati jẹ igbakeji ọga agba fun ti isakoso.
“Ki awọn awọn to n ka iroyin le
gbagbọ pe irọ lawọn eeyan yii n pa nigba ti mo gbe igbesẹ lati jẹ ka di ọkan mo
b Ṣọji Ganzallo, to jẹ olori So-Safe Corps sọrọ, bẹẹ naa ni mo tun ba Gbenga
Adesanya to jẹ ọga agba fijilante ti igun Ali Sokoto ati Nureni Adedoyin toun jẹ
ti Jahun naa ṣepade pọ.
Lẹyin naa lo sọ pe oun Ganzallo,
Adesanya ati Adedoyin ṣepade pọ pẹlu igbakeji ọga ọlọpaa patapata Oluṣọla Subair, to jẹ oludamọran
gomina lori eto abo ṣepade pọ. Nibẹ ni gba
ti wọn niyanju lati yan aṣaaju fun ti ki wọn di ọkan yii.
O ni loju
ẹsẹ loun ti sọ fun wọn ki wọn jẹ koun wa nipo alakoso toun wa ki Adedoyin, Ganzallo
ati Adesanya yan olori laaarin ara wọn. Ọkunrin naa tun ṣalaye pe loju ẹsẹ
lawọn mẹtẹẹta wọ yara kan lọ ti Adedoyin si ni ki Ganzallo jẹ gẹgẹ bi ọga agba,
oun si gba koun jẹ igbakeji fun isakoso nigba ti Adesanya si jẹ igbakeji ọpureṣan
ti gbogbo wọn si fẹnu ko lee lori. Ti Oluṣọla Subar si fọwọ sawọn ipo ọhun.
Ṣodiyan ni bawọn ṣe pari lọjọ naa
lawọn gba iwe iroyin lọ fun ajọyọ tawọn si tun ya fọto pẹlu.O ni lori ọrọ ti
Ọlawale to ṣebi ẹni pe oun ko mọ oun ri
ninu ọrọ to sọ pe ṣe o ti gbagbe pe titi di akoko yii lo ṣi n gbowo, ẹgbẹrun lọna
igba naira lọwọ oun loṣooṣu gẹgẹ bi owo awọn oṣiṣẹ fijilante to n ṣiṣẹ pẹlu oun.
O lawọn sunmọ
ara awọn daadaa ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ bo ṣe jẹ ki wọn fa oun kalẹ gẹgẹ bi ohun elo.
O ni wọn kan wa awọn irọ kan papọ ki awọn araalu le ro pe wọn jẹ ẹnikan pataki
laimọ pe otubantẹ ni wọn, ti imọtara-ẹni nikan si pọ fun wọn.
O wa rọ awọn araalu ki wọn da awọn ọrọ
ti wọn danu bi omi iṣanwọ nitori wọn ko ni nnkankan ti wọn fẹẹ ṣe fawọn araalu.
O ni oun ko raye tiwọn nitori ipolowo ki wọn le mọ wọn ni wọn n wa kaakiri ni
wọn fi n ṣe ibajẹ.
Odara lati je olooto ni gbogbo ona
ReplyDelete