Idunnu ṣubu layọ fẹgbẹ awọn oniroyin ‘Federated’ nipinlẹ Ogun, lọjọ Aje, Monde, ọsẹ yii nigba wọn dibo yan Ọgbẹni Lanre Adegboyega, ti iwe iroyin National Standard, gẹgẹ bi alaga tuntun fẹgbẹ awọn oniroyin naa.
Nibi ibo naa to waye ni ọfiisi awọn aṣoju-kọrọyin, ti wọn
jo n lo pẹlu Federated, laduugbọ Nawwal-Ud-Deen, Iṣabọ, niluu Abẹokuta ni ọkunrin
naa ti jawe olubori laini alatako kankan.
Ki idibo naa to waye ni alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ, Ọgbẹni Niyi
Adeloye, ti dupẹ lọwọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ fun atilẹyin wọn lakooko toun fi wa
nipo naa laaarin ọdun mẹta.
O ni ọpọ ojo lo ti rọ tilẹ ti fi mu omi ṣugbọn oun dupẹ
fawọn aṣeyọri nla ti Ọlorun tori oun ṣe yii. O wa sọ pe ibo to waye lọjọ naa jẹ
atẹwọgba labẹ ofin ẹgbẹ awọn oniroyin, nitori ko si ninu ofin pe awọn ẹkun ti wọn
pe ni Zonal ni
ko wa ṣe eto idibo fun Federated.
O ni niwọngba to jẹ pe Ọgbẹni Ṣoji Amosun ni ile-ẹjọ ṣi
gba lati maa ṣakoso ẹgbẹ awọn oniroyin oun lo lẹtọọ lati ṣeto ibo, idi niyii to
fi jẹ awọn iṣakoso ọkunrin yii lo wa ṣeto ibo naa.
Lara awọn to tun jawe olubori nibi ibo ọhun ni Ọmọtọlani
Lawal fun igbakeji ẹgbẹ, Kayọde Akin Samuel ni akọwe ẹgbẹ nigba ti Lekan Lisoye
jẹ igbakeji akọwe ẹgbẹ.Ṣọla Ajibikẹ ni akapo, Oluwafẹmi Abiọdun ṣi ni akọwe iṣuna
ti Dauworthy Fathia wa jẹ oluyẹwe owo wo.
Ninu ọrọ alaga tuntun naa, Ọgbẹni Lanre Adegboyega, o dupẹ
lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ fun bi wọn ṣe fibo gbe oun wọle lọjọ naa.Pẹlu pe gbogbo
ileri toun ṣe lakooko alẹ nnkan bayi ni maa ṣe ti mo ba dori ipo iyẹn manifesto
loun yoo ri pe oun muṣẹ.
Ati pe nnkan akọkọ to jẹ oun logun bayii ni bi irẹpọ yoo ṣe
tẹsiwaju ninu ẹgbẹ naa.
Ni bayii awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wa kede pe Lanre Adegboyega
to wọle gẹgẹ bi ilana ati ofin ẹgbẹ awọn oniroyin nikan ni ojulowo alaga fẹgbẹ ọhun
ati pe ẹnikẹni to pa ba tun pe ara ẹ nipo naa ojulowo ayederu ni onitọhun.
No comments:
Post a Comment