Lati le ran ijọba ipinlẹ Ọyọ, lọwọ
lori igbogun ti arun koronafairọọsi lawọn ileewe alakọbẹrẹ ati ti girama ki wọn
le maa ri ohun elo to le dena arun naa, idile Arulogun, ti ṣeto iranlọwọ ẹbun
fawọn ileewe to wa niluu Arulogun naa.
Nibi eto naa to
waye ni Mogaji ẹbi ọhun to tun jẹ Jagun Balogun ilẹ Ibadan, Oloye Monsur, ti
ṣaaju awọn Baalẹ yooku lọ fawọn ileewe yii lẹbun. Nibẹ lo ti fi aidunnu ẹ lori
ijamba ti arun korona yii le mu bawọn akẹkọọ, ti wọn ko ba tete wa nnkan to le
dena ẹ.
Awọn ẹbun
ti wọn fi ṣeranwọ fawọn ileewe ọhun ni ibomu, ifọwọ, ibọwọ, ike ipọnmi si atawọn
nnkan mii in. Bakan naa ni wọn tun lo akoko yii lati gba awọn akẹkọọ nimọran,
ọna ti wọn le gba dẹkun arun koronafairọọsi.
Nigba to n
bawọn oniroyin sọrọ,Oloye Monsur sọ pe mọlẹbi Arulogun gbe igbesẹ naa lati fi
atilẹyin wọn han sijọba Ṣeyi Makinde, to jẹ gomina ipinlẹ naa, ọna tawọn ṣi le
gba fi ẹmi imoore han ni pe kawọn fọwọsowọpọ pẹlu ẹ lati fi gbogun ti arun
korona yii
O ni ‘Awọn ileewe ti wọle pada
nipinlẹ Ọyọ,a ni lati rii pe abo to peye wa lori wọn pẹlu alakalẹ igbesẹ tijọba
fi silẹ. A ṣẹṣẹ bẹrẹ ni ninu idile wa, a o si maa sa ipa wa loorekoore”
Inu awọn ọmọleewe lo dun si awọn
mọlẹbi foun ti wọn ṣe fun wọn to si tun jẹ iyalẹnu fun wọn pẹlu.
Awọn yooku to
tun tẹle mọgaji lọ ni Oloye Timothy
Oluyọmbọ Arulogun, Baalẹ ti wọn ṣẹṣẹ yan, Arulogun 1 ati Oloye Lawal Taofeq Arulogun
Baalẹ- ti Arulogun Ilu-ọja town atawọn mii in.
|
||
No comments:
Post a Comment