Gbogbo eto lo ti pari bayii, fun eto idibo lati yan oloye ẹgbẹ tuntun fawọn ọmọ ẹgbẹ oniroyin Federated, nipinlẹ Ogun. Eyi ti yoo waye lọjọ Aje, Monde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, osu yii.
Gẹgẹ bi atẹjade ti Oloye Ṣina Ọduntan, akọwe igbimọ to
ṣeto ibo naa fi sita lonii, ọjọ Abamẹta, Satide, lo ti ṣalaye lẹkunrẹrẹ pe ọjọ
naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa yoo fibo wọn gbe ẹni ti wọn ni lọkan wọle.
Ọfiisi aṣoju-kọroyin to wa ni Nawwal-Ud-Deen, Iṣabọ,
niluu Abẹokuta ni ibo ọhun yoo ti waye bẹrẹ ni deede ago mẹwaa aarọ di aago
meji ọsan.
Loju ẹsẹ ti wọn ba ti kede ibo tan ni wọn yoo ṣebura
fawọn oloye tuntun.
Bakan naa lọjọ naa ni Ọgbẹni Adeniyi Adeloye, to jẹ alaga
ẹgbẹ naa yoo gbejọba kalẹ fawọn oloye tuntun.
Lara awọn ti yoo wa nibẹ lati mọ bi nnkan ba ṣe n lọ ni
Ọgbẹni Ṣọji Amosun, ojulowo alaga fẹgbẹ awọn oniroyin nipinlẹ Ogun, oun ni yoo
si fa alaga to ba jawe olubori soke pẹlu Adeloye ti yoo gbejọba kalẹ.
No comments:
Post a Comment