Arakunrin kan, ẹni ọdun marundinlogoji, Ọlalere, to n gbe ni ojule kejidinlogun,Unity,Olowotẹdp, Mowe, nipinlẹ Ogun, nile-ẹjọ ti paṣẹ pe ko lọ lo gbogbo igbesi aye ẹ yooku lọgba ẹwọn nitori to fipa bọmọ ọdun meji sun.
Nigba to n gbe idajọ ẹ kalẹ lọsẹ to kọja, Onidajọ Abiọdun Akinyẹmi, sọ pe ko si awitunwi kankan, Ọlalere, jẹbi ẹsun ti wọn si kan an naa, pẹlu gbogbo ẹri to wa niwaju oun yii, ko si maa lọ si ẹwọn egbere.
Gẹgẹ bi
agbẹjọro ijọba, Oluwayẹmisi Aruleba, ṣe wi nile-ẹjọ nigba ti igbẹjọ n lọ
lọwọ,lọjọ kejilelogun, oṣu kẹta,ọdun 2017, ni wọn sọ pe Ọlalere huwa ibi naa
lojule kejidinlogun, Baṣọrun, Unity, Olowotẹdo,ni Mowe nipinlẹ Ogun.
O ni iya ọmọ
naa n gbe ile kan naa pẹlu ọkunrin naa, nitori o n ran an lọwọ lati baa ta
ounjẹ. O ni ṣadeede ni iya ọmọ naa ri ọmọ ẹ to n sunkun, to si tun sakiyesi pe
ko le rin daadaa, ti nnkan si n da labẹ ọmọ naa.
O fikun ọrọ ẹ
niwaju Adajọ pe iya ọmọ naa mu ọmọ yii lọ si ọsibitu nibi ti wọn ti sọ fun un
pe atọ ọmọkunriin wa labẹ ọmọ naa pe wọn ti fi tipa baa sun.
No comments:
Post a Comment