Beeyan ba jori
ahun ko si ki omi maa bọ loju ẹ, to ba debi ti ijamba kan ti ṣẹlẹ nigba ti mọto
ko sodo Ọsọsa lọna Ṣagamu si Ijẹbu-Ode, nibi tawọn mẹrin ti padanu ẹmi wọn
tawọn kan si tun farapa yannayanna.
Gẹgẹ bi iwadii
wa,mọto Opel to n ko awọn arinrinajo bọ lati Ijẹbu-Ode lọ si Sagamu, lo ṣadeede
ko sodo lojiji. Wọn ni ere asapajude to sa lọjọ lo ṣokunfa, ti ijanu ọkọ ẹ fi
ja lojiji.
Loju ẹsẹ ni wọn
sọ pe awọn eeyan mẹrin naa ti doloogbe,nigba tawọn mẹfa si farapa, ti wọn si ko
wọn lọ si ọsibitu jẹnẹra to wa ni Ijẹbu-Ode nibi ti wọn ti n gba itọju, tawọn
to ku si wa ni mọsuari.
Agbẹnusọ awọn
TRACE, Ọgbẹni Akinbiyi, to ba wa sọrọ nipa iṣẹlẹ naa sọ pe awọn ti gba mọto naa
jade kuro ninu odo tawọn si waa lọ ẹka to n ri si ọrọ mọto ni Odogbolu.
O wa lo akoko
naa lati bawọn ẹbi ti wọn doloogbe kẹdun to si tun kilọ fawọn onimọto lati
dẹkun ere asapajude loju popo lakooko ojo taa wa yii.
No comments:
Post a Comment