Awọn adigunjale
meji kan,ti wọn ko mọ ju ki wọn ji ọkada lọ ki wọn si ta loju ẹsẹ ni agbegbe
Ijẹbu-Ode, Joshua Micheal ati Emeka Nwanga lọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ, ti wọn si ti
n ka boroboro bayii
Logunjọ, oṣu
yii, lọwọ awọn ọlọpaa digboluja to wa ni Ilese-Ijẹbu tẹ awọn eeyan ọhun. Gẹgẹ
bi atẹjade to jade lati ọdọ awọn ọlọpaa ni wọn ti sọ pe awọn tọwọ tẹ yii ni wọn
ti kopa ninu jiji ọkada kaakiri gbogbo ilu Ijẹbu Ode.
Wọn ni lakooko
ti wọn gbidanwo lati ji ọkada mii in lagbegbe Ikangba, ni wọn ta awọn ọlọpaa
lolobo, eyi to mu ki Olusesi Kayọde, ọga awọn ọlọpaa agbegbe ṣaaju awọn eeyan ẹ
lọ sibẹ
Bi awọn
adigunjale yii ṣe ri awọn ọlọpaa ni wọn sa lọ tawọn ọlọpaa si gba tẹle wọn pẹlu
iranlọwọ awọn araalu, ti wọn si mu wọn.
Loju ẹsẹ ni wọn
si bẹrẹ iwadii le wọn lori tawọn tọwọ tẹ naa si jẹwọọ pe loootọ lawọn ko niṣẹ meji ju kawọn ji ọkada, kawọn si tun
ta. Kọmisanna awọn ọlọpaa si ti paṣẹ pe ki wọn ko awọn eeyan naa wa si
Eleweran, niluu Abẹokuta, ki iwadii si tẹ siwaju.
No comments:
Post a Comment