Ọrọ buruku toun tẹrin ni iṣẹlẹ to waye ni Idọgọ nijọba ibilẹ Yewa South, nigba tọwọ tẹ Arakunrin kan, Zenitieni Sojinen, ẹni to ji ọkada, to tun jẹ pe oun naa lo tun ṣaaju awọn ẹni to n wa ọkada naa.
Gẹgẹ bi iroyin
to tẹ wa lọwọ.ọkada kan to jẹ ti ọkan lara awọn ọlọpaa to wa ni Ilaro, Joseph
Micheal, ni wọn sọ pe wọn ji lọ ni oko kan ni Ileba, Ilaro nijọba ibilẹ Yewa
South.
Loju ẹsẹ si la
gbọ pe Sọji Ganzallo, to jẹ ọga agba fajọ alaabo
So-Safe ti paṣẹ fawọn ọmọọṣe lati sawari ọkada naa, nibi ti wọn ba ti ji i gbe.
Aṣẹ yii lawọn oṣiṣẹ naa tẹle pẹlu ẹni ti wọn ji ọkada ẹ yii.
Ohun to wa jẹ
kayefi nibẹ ni pe ẹni to ji ọkada naa lo tun ṣaaju awọn eeyan maa wa ọkada yii,
oun gan-an naa lo mu wọn de ibi ti ọkada naa wa ninu oko kan to tọju ẹ pamọ si
ni Ahmadiya, Idọgọ.
Ninu iwadii
awọn So-Safe Corps ni aṣiri ti tu pe ẹni to mu awọn debi ti ọkada ti nọmba ẹ jẹ
IE501MB595181 gan-an ni ọwọ ẹ ko mọ si, ti wọn si faa le awọn lọwọ ni teṣan wọn
to wa ni Ilaro.
Nibẹ si ni wọn
sọ pe ọkunrin naa ti jẹwọ pe loootọ oun loun ji ọkada naa ati pe ẹri ọkan ni ko
jẹ koun gbadun. Ni bayii, awọn ọlọpaa ti n ba iwadii wọn lọ.
No comments:
Post a Comment