Lana an, Ọjọruu,
Wẹsidee, la gbọ pe wahala kan bẹ silẹ ni Ojodu Berger, laaarin awọn ọlọkada ati
awọn ọlọpaa nibi ti ibọn ti ba ọkan lara awọn Hausa, to jẹ ọlọkada, torukọ ẹ jẹ
Abdulahi, tawọn mẹta mii in tun farapa.
Ariwo ti wọn n
pa ni ẹgbẹ ọlọkada Riders and Owners of Motorcycles
Organization,ti wọn n pe ni ROMO, lo da wahala naa silẹ, nitori tikẹẹti. Ṣugbọn
alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, Alaaji Ọnarebu Ṣotayọ Raṣak Oluṣọla,tọpọ mọ si Ṣolebọ ti sọ pe ko
si ootọ ọrọ Kankan ninu ẹ ati pe bọrọ ṣe jẹ niyii
O sọrọ yii
lakooko to n fọrọ jomitoro ọrọ pẹlu oniroyin wa, o sọ pe ẹgbẹ ọlọkada ROMO, ti
n ṣiṣẹ nibẹ latigba ti wọn ti da ẹgbẹ naa silẹ,ti ko si wahala ṣugbọn awọn ẹgbẹ
awọn onimọto National lati Eko, ni wọn n wọ ilẹ ipinlẹ Ogun, lati fẹẹ ma wa fun
awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọkada, kẹkẹ ni tikẹẹti lori ilẹ ipinlẹ Ogun.
O ni ṣe ẹ mọ pe
wọn ti fofin de awọn ọlọkada ni Eko, ọna abayọ ẹ lawọn ọmọ Hausa yẹn n lo ti
wọn fi sa wa sori ilẹ ipinlẹ Ogun, tawọn onimnto Ekoo yii si fẹ maa n ja iwe
fun wọn, ti wọn si n lo agbegbe yẹn.
Ọkunrin naa tun
ṣalaye pe nigba tawọn de bẹ, awọn fopin si gbogbo wahala yẹn, ki rogbodiyan ko
ma ba a maa waye, awọn si ni ki wọn duro lori ilẹ wọn, ki ipinlẹ Ogun naa duro
lori ilẹ ẹ.
Ṣolebọ tun
fikun ọrọ ẹ pe ‘Awọn Hausa yẹn, ṣe ẹ mọ pe wọn ko gbọ nnkankan, wọn wa fun wọn
ni iwe, nigba ti wọn ba ja a fun wọn, ti
wọn pada, ẹni taa mu to jẹ ọmọ National, to ṣe tikẹẹti ayederu ROMO, to ko
gbogbo ẹ sọwọ, Monsuru Ọlabisi lorukọ ẹ.’’
O ni oun ni ki
wọn fọlọpaa muu, ki wọn ti mọle, ṣe lawọn ẹbi ẹ wa, ti wọn wa bẹbẹ, tawọn ni ko
kọwọ bọwe pe oun ko ni ṣeru ẹ mọ. Nigba ti oloye ẹgbẹ awọn kan gbọ pe Mọnsuru
yii tun wa ṣe ipade pọ pẹlu awọn kan ni alẹ ijẹta mọjumọ ana.
Iyẹn lo sọ pe o
sọ fawọn ọlọpaa pe oun gbọ nnkan bayii o, ti ọmọ ti wọn fi silẹ ba tun le da
wahala mii in silẹ, awọn ko ni gba fun un.
Alaga naa ni ‘Bo
ṣe di ni aarọ ana, o dabi pe awọn ọmọ Hausa yẹn,wọn lawọn ko fẹ gba ki wọn
dawọn pada si Eko mọ, awọn yẹn lo wa lọ doju ija kọ awọn ọlọpaa ni teṣan wọn,
ko to di pe wahala bẹ silẹ laaarin wọn’’.
O fidi ẹ mulẹ
pe ki i ṣe pe ọlọpaa lọ ba awọn Hausa ọhun, awọn lo lọ ba ọlọpaa, nitori ti wọn
gba ọkada wọn, awọn lo lọ doju ija kọ wọn. Oun lawọn ọlọpaa fi jade si wọn.Boya
ibi ti wọn ti n lọ ibọn mọ wọn lọwọ ni wahala ti ṣẹlẹ. Ọmọ Nasarawa lo ni wọn n
pe awọn Hausa yii.
Ṣolebọ ni ‘Ati
Eko ni wọn ti wa si ipinlẹ Ogun, latigba
taa ti mọ lati gbe igbesẹ pe ni osẹ ti wa, a o le gba keeyan maa gbe
tikẹẹti Eko ko wa ma ja ni ipinlẹ Ogun. Ki i ṣe awa atawọn ọlọpaa la jọ kọju
ija sira wa.
O wa pari ọrọ ẹ
pe nibi ti ọrọ naa de bayii, ọga awọn ọlọpaa agbegbe tiṣẹlẹ naa ti waye, ti gbe
ẹjọ ọhun lọ si Eleweran. O ni awọn Hausa to gun ọkada lo da wahala silẹ, ti wọn
koju ọlọpaa ki i ṣẹgbẹ ROMO.
No comments:
Post a Comment