Bo tilẹ jẹ pe lọsẹ meji sẹyin to yẹ ki Gomina Dapọ Abiodun bawọn oniroyin sọrọ gẹgẹ bo ṣe maa n ṣe lati jẹ ki wọn mọ ibi ti nnkan de lori ọrọ arun korona, ọkunrin naa ko ṣe bẹẹ, akọwe iroyin ẹ lo gbe atejade kan sita lati fi ọsẹ meji kun awọn ilana to ti wa nilẹ.
Erongba awọn araalu ni pe loni in ti ọsẹ naa pe ti wọn si
ti n woye nnkan ti Gomina yoo bawọn sọ ati igbesẹ ti wọn yoo tun tẹle, iyalẹnu
lo jẹ pe titi di akoko yii, wọn ko ti gbọ nnkankan, eyi to si ti sọ wọn sinu
igbekun.
Gẹgẹ bi iwadii wa, lati ọsan lawọn oniroyin ti n woye
lati mọ igba ati akoko ti Gomina Dapọ Abiọdun yoo pe awọn lati le sọ fawọn
araalu nibi ti nnkan duro de.
Ṣugbọn nnkan taa n gbọ ni pe wọn ni Gomina ko si ni Abẹokuta
depodepo pe imurasilẹ wa lati jẹ kawọn araalu mọ ibi tijọba ipinlẹ Ogun ba iṣẹ
de lori ọrọ arun koronafairọọsi to gbilẹ yii.
Ibeeere tawọn araalu n beere ni pe ki lo de tijọba to wa
lode naa fi n fawọn sinu okunkun, eyi ti ko jẹ ki ọpọ araalu mọ nnkan ti wọn
yoo ṣe, ti gbogbo ẹ si duro soju kan.
Ohun tawọn araalu n woye le lori to jẹ wọn lọkan ju ni
igba ati akoko ti wọn yoo ṣi ile-ijọsin ti wọn ti tipa lati bi oṣu mẹrin sẹyin,
ati awọn ileewe gbogbo ti wọn ti tipa.
Bẹẹ ni wọn fẹẹ mọ ibi tọrọ korona gan-an duro de nipinlẹ
naa, ti ọpọ araalu ko le sọ pato, eyi ti wọn sọ pe awọn ipinlẹ yooku ko ṣe, wọn
ni ṣe lọrọ naa dabi ẹni pe kinni ọhun ko fẹẹ ye ijọba mọ funra wọn.
Nitori ko yẹ ki wọn wa sọ awọn araalu sinu igbekun, ti wọn
yoo si maa lo awọn ofin onikondo le wọn lori.
No comments:
Post a Comment