Alagba Rasheed Oyejọbi, to jẹ ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe Isreal Olumide Oyejọbi ti ṣapejuwe Baba wọn gẹgẹ bi ẹni to fi awokọṣe rere silẹ nigba ti wọn wa laye, toun ko si le gbagbe wọn titi lai.
O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ nibi ayẹyẹ
isiniku Baba naa to waye ni Isalẹ- Abẹtu, niluu Abẹokuta, nibi tawọn ara, ọrẹ
ati ojulumọ ti peju pesẹ lati bawọn ṣayẹyẹ ọhun.
Rasheed sọ pe aimọye nnkan loun jogun lọdo baba oun, to
si wulo foun di oni yii, nitori o ni wọn jẹ ẹnikan ti ko fẹran imẹlẹ, gbogbo
igba ọjọ aye wọn lo ni wọn fi jẹ akikanju.
O ni Baba to
bi oun jẹ onirẹlẹ eeyan, to si ni itẹriba, o ni o kawe niwọnba diẹ,
o si ṣiṣẹ olukọni, nigba to fiṣẹ naa silẹ lo ni o pada lọ si abule ti wọn ti
bii ni ọna Ọbafẹ, Ṣowẹmimọ lo ni wọn pe abule ọhun.
Iṣẹ agbẹ lo ni wọn n ṣe lọhun lati maa ri nnkan jẹ,
ati lati maa fi tọju awọn ọmọ, iṣẹ yii
lo sọ pe wọn n ṣe titi digba ti ọlọjọ fi de. Lara ẹkọ toun kọ lọdọ Baba oun ni
keeyan ni iforiti, ko si jẹ olootọ.
O ni Baba oun tun fọna iwe han oun, to si fiṣẹ toun ṣe le
oun lọwọ. Gbogbo nnkan lo ni Baba fi kọ oun, bo ṣe tọ oun nipa tiwe lo tun fiṣẹ
agbẹ le oun lọwọ pẹlu.
Ninu gbogbo ọmọ to ni Isreal Oyejọbi bi, oun nikan loun
ya si iṣẹ agbẹ toun si n jẹ ere ẹ titi di oni yii. Ọkan ninu awọn ọmọ Baba naa,
toun jẹ akọbi ẹ lobinrin, Iyaafin Florence Oluwayẹmisi Sanyaolu Oyejọbi, o ṣapejuwe
baba ẹ gẹgẹ bi ẹni ti ki i fọrọ ọmọ ẹ ṣere.
O ni bo tilẹ jẹ pe awọn ko gbọnju mọ iya awọn ṣugbọn Baba
yii ko jẹ kawọn mọ ala debi pe gbogbo igba toun ba bimọ, ṣe ni yoo wa jokoo
toun.
O ni baba oun nifẹẹ oun pupọ nigba to wa laye oun ko le
gbagbe ẹ.
No comments:
Post a Comment