Fẹmi Omilani di alaga awọn sọrọsọrọ FIBAN nipinlẹ Ogun fun igba keji - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 17 July 2020

Fẹmi Omilani di alaga awọn sọrọsọrọ FIBAN nipinlẹ Ogun fun igba keji
Lọjọ Ẹti, Furaidee, oni yii, ni ẹgbẹ awọn sọrọsọrọ nipinlẹ Ogun, iyẹn FIBAN, tun dibo yan,Ọgbẹni Olufẹmi Omilani, gẹgẹ bi alaga wọn fun igba keji.

Nibi ibo ẹgbẹ naa to waye ni ọfiisi wọn to wa ni Nawal-Ud-Deen, Iṣabọ, niluu Abẹokuta, nibi ti Ọgbẹni Olufẹmi Daisi ti ṣakoso ẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ  naa ti fi ibo wọn sọ pe ki ọkunrin naa maa ba iṣẹ ẹ lọ nigbakeji gẹgẹ bi adari laini alatako.

Lara awọn ti wọn tun dibo yan wọle ni  Ẹniọla Ogunsanya toun wọl ẹ gẹgẹ bi igbakeji alaga. Muristq Oluwatosin si jẹ akọwe ẹgbẹ, Rasheed Ọjẹlabi Orẹọba ni Akapo ẹgbẹ tuntun fawọn sọrọsọrọ.

Awọn yooku ti wọn yoo tun jọ ṣiṣẹ pọ ni Olumayọwa Abajingin toun naa wọle laini alatako gẹgẹ bi akọwe olupolongo. Kikẹlọmọ Ogunṣina ni alamojuto,Mosses Okunọla ni akọwe eto isuna, Saheed Tajudeen Oloṣelu si di igbakeji akọwe ẹgbẹ.

Olusọji Akindiya ni akọwe oluṣeto fẹgbẹ nigba ti Ọlawale Ampitan di ọlọpaa ẹgbẹ. Gbogbo wọn ni wọn wọle laini alatako kankan.

Ninu ọrọ alaga ẹgbẹ ẹgbẹ naa, Fẹmi Omilani, lo ti dupẹ lọwọ awọn eeyan ẹ fun bi wọn ṣe tun dibo yan an lẹẹkeji. O wa mu dawọn loju pe oun ko tun ni jawọn ni tan an mọ.

Bẹẹ lo tun sọ pe gẹgẹ bi ipo ti wọn yan oun si gbogbo ọna loun yoo maa sa lati ri pe ilọsiwaju ati idagbasoke fojoojumọ de ba ẹgbẹ awọn sọrọsọrọ nipinlẹ Ogun.

No comments:

Post a Comment

Pages