Ọwọ alaabo ilu So Safe Corp, ti tẹ ọkunrin afurasi kan, Oluwatosin Abọwaba, ti inagijẹ n jẹ Maja, ẹni tawọn ọlọpaa Ijẹbu-Ode ati Mowe n wa pe o jẹ ogbologbo adigunjale to n ji ọkada kaakiri.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Lọjọruu, Wẹsidee, osẹ to kọja lọwọ awọn alaabo naa tẹ ọkunrin yii lagbegbe Olowotẹdo, ni Mowe, ti wọn si ti faa fawọn ọlọpaa fun iṣẹ iwadii.
Iwadii fi ye wa
pe oriṣiriṣi awọn iwa ọdaran ni wọn sọ pe afurasi naa ti kopa n inu ẹ paapaa
julọ nipa jiji ọkada lawọn agbegbe Mowe ati ni Ijẹbu.
Awọn tọwọ ti tẹ ti wọn wa ni atimọle
awọn ọlọpaa ni wọn jẹwọ pe Tosin ti wọn mu yii lo maa n ji ọkada to si maa n
tun ta fawọn, tabi kawọn ba oun wa ẹni ti yoo ba ra a.
Ninu ọrọ Moruf Yusuf, agbẹnusọ fajọ alaabo So Safe Corp, nipinlẹ
Ogun, lo tun ti ṣalaye pe aimọye ọkada ni Tosin ti ji ni Mowe, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi-Owode
to si gbe lọ si Ijẹbu- Ode lati tun ta.
Ohun ti wọn lo n jẹ ki o maa ri
ọkada naa ji gbe ni pe o maa n ja tikẹẹti fawọn ọlọkada ni Mowe, nibẹ ni wọn lo
ti maa n foju si awọn tikẹẹti to fẹ ji gbe.
Lara awọn nnkan ti wọn ri gba lọwọ
ẹ to fi n ṣiṣẹ ibi ni ada, ọbẹ, irin atawọn ogun ija oloro. Ni bayii, wọn ti
fa le awọn ọlọpaa Ọbafẹmi Owode, lọwọ ti iwadii si ti n tẹ siwaju.
|
No comments:
Post a Comment