Ọpẹ o; Ẹniọla Ṣodiya sọrọsọrọ ori redio Rockcity moribọ lọwọ arun koronafairọọsi. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 16 July 2020

Ọpẹ o; Ẹniọla Ṣodiya sọrọsọrọ ori redio Rockcity moribọ lọwọ arun koronafairọọsi.



Lọsẹ meji sẹyin la gbe iroyin kan jade nipa sọrọsọrọ ori redio nni Ẹniọla Anikẹ Ṣodiya tawọn oloolufẹ ẹ mọ si Iyalode pedepede pe o ni arun to n tan kaa nni, koronafairọọsi, ti wọn si ti n tọju ẹ. Sugbọn pẹlu idunnu la fi sọ pe obinrin naa ti moribọ, ara ẹ si ti ya.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lẹyin ti obinrin naa ti gba itọju to peye lori aisan ti wọn lo wa lara ẹ naa, ni wọn tun lọ ṣayẹwo mii in fun-un, eyi ti wọn lesi ẹ jade pe ko si arun naa mọ lara ẹ, ko m lọ maa jẹ amala ati ọbẹ ewedu bo ṣe n jẹ tẹlẹ.

Ohun ta gbọ ni pe latigba ti Anikẹ ti wa ninu ile ni wọn ti n fun lawọn ogun, ti wọn si lawọn ogun naa ṣiṣẹ sii lara, koda inu idunuu ati ayọ gan-an ni wọn sọ pe oun naa wa bayii.

Nigba toun gan-an ba wa sọrọ lori foonu, o sọ pe oun ko le ṣapejuwe bi inu oun ti dun to, nitori aisan korona kii ṣe nnkan kekere, o loun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko jẹ ki koronafairọọsi mu ẹmi oun lọ.

Bo tilẹ jẹ pe o lawọn eeyan kan ko nigbagbọ pe aisan naa wa ṣugbọn pẹlu awọn iriri toun ri lakooko naa oun gbagbọ pe loootọ ni korona yii n ja, awọn ti kinni ọhun kan, toun jẹ ọkan ninu wọn lo le sọ.

O wa dupẹ lọwọ gbogbo awọn oloolufẹ ti wọn fadura han oun lọwọ, tọpọ si n pe lakooko naa pe arun naa ko nii ya ile onikaluku wọn ati pe kawọn naa pa ofin to rọ mọ mo, nitori korona fairọọsi, ki i ṣe nnkan teeyan le foju parẹ.



No comments:

Post a Comment

Pages