Ọgbẹni Sunday Ọlapọsi Ọginni, to jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu New
Nigeria Political Party, NNPP, nipinlẹ Ogun, ti sọ pe iṣẹkiṣẹ ati pakute iku ni
biriji ti Dapọ Abiọdun ṣe, ti ko tii pe ọdun kan, si Ọpako lọna Adigbẹ, to ti
dawolẹ bayii jẹ fawọn araalu, ti ko si bojumu.
Ninu atẹjade kan ti alaga naa fi sita lo ti sọ pe ẹdun ọkan
lo jẹ fawọn araalu ati ẹgbẹ oṣelu naa pe ijọba to wa lode le ṣe iru iṣẹ
ajanbaku yii, eyi to fi han pe wọn kan fẹẹ ma na owo ijọba ni inakuna pẹlu awọn
iṣẹkiṣẹ yii.
O ni bi a ko ba ni parọ, o yẹ ki Dapọ Abiọdun tọrọ idariji
lọdọ awọn awọn araalu lori nnkan to ṣẹlẹ naa.O lou n ka kun aimọto isejọba to
wa lode yii.
Ọginni tun sọ pe nnkan toun sọ nigba kan niyẹn pe ijọba
to wa lode yii ko kun oju oṣuwọn lati gba ẹyawo biliọnu aadọta-le- nigba naira ẹyawo
ti wọn fẹẹ gba, nitori awọn mọ pe inakuna ni wọn fẹẹ na.
A o ranti pe lọdun to kọja, nijoba Dapọ Abiọdun bẹrẹ iṣẹ
lori afara iyẹn biriji to wa ni Ọpako-Adigbẹ fawọn araalu lati maa gba ibẹ kọja,
ṣugbọn o ṣe ni laanu pe agbara ojo gbe gbogbo afara naa lọ, lai pe ọdun kan ti
wọn bẹrẹ ẹ.
Gbogbo awọn to si n gbe laduugbo naa ni inu wọn ko dun si
nnkan to ṣẹlẹ naa. Ni bayii, a gbọ pe gbogbo ọna nijọba fi n wa atunṣe si ọna
naa, tiṣẹ si ti bẹrẹ ni pẹrẹu
No comments:
Post a Comment