Bayọ Dayọ pẹjọ kotẹmilọrun lori bi Adajọ ṣe fagile ẹjọ to pe - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 7 July 2020

Bayọ Dayọ pẹjọ kotẹmilọrun lori bi Adajọ ṣe fagile ẹjọ to pe




Oloye Bayọ Dayọ, alaga fẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun, to ṣẹṣẹ fẹ kogba wọle ti pẹjọ kotẹmillọrun lori idajọ kan to wa ni kootu giga kan niluu Ijẹbu Ode, lọsẹ to kọja nibi ti Adajọ to n gbẹjọ  to pe Buruji Kashamu ati igbakeji ọga agba fawọn ọlọpaa ti ẹkun keji ti fagile ẹjọ naa.

Lọjọ Mọnde, ọsẹ yii ni Oloye Bayọ Dayọ gba ileẹjo kotẹmilọrun to wa niluu Ibadan pe  bi Adajọ to gbẹjọ naa iyẹn O S Olusanya, ṣe fagile ẹjọ toun pe naa ko tẹ oun lọrun, oun si fẹẹ kawọn Adajo kotẹmilọrun naa wo ẹjọ naa daadaa, ki wọn si ṣe idajọ to yẹ le lori.

Ninu iwe ẹjọ naa ti nọmba ẹ jẹ NCJ/64/2020 ni lawọn ko ti gba ọna ti Adajọ naa gba fagile ẹjọ naa paapaa ni abala kẹta iwe ipẹjọ ọhun. Ti wọn si rọ ile ẹjọ naa lati jẹ ki igbẹjọ waye lori ti abala kẹrin iwe naa.

A o ranti pe Oloye Bayọ Dayọ  ati ọmọ ẹ lo pe Buruji Kashamu ati igbakeji ọga ọlọpaa ti ẹkun keji lẹjọ lori ọna meji ọtọọtọ, akọkọ ni lati ma jẹ ki Buruji Kashamu fọlọpaa mu awọn tabi ti wọn mọle lori ẹjọ to fi sun.

 Ẹlẹẹkeji ni pe olujẹjọ, iyẹn Kashamu fẹẹ lodi si ofin to nii ṣe omininira ọmọniyan ati dukia ti ko si yẹ ko ri bẹẹ ṣugbon ṣe ni Adajọ naa fagile ẹsun mejeeji, idi niyii ti Dayọ Bayọ ṣe gba korẹmilọrun lọ pe igbesẹ Adajọ  to fagile ẹjọ naa ku diẹ kaato, oun ko gba.

Ni bayii, ileẹjọ kotẹmilọrun to wa ni Ibadan, si ti tẹwọgba iwe ipẹjọ naa, ti iṣẹ si ti bẹrẹ lori ẹ kiakia.

No comments:

Post a Comment

Pages