Idi taa ṣe fọsẹ meji kun awọn igbesẹ to wa nilẹ lori arun koronafairọọsi. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 4 July 2020

Idi taa ṣe fọsẹ meji kun awọn igbesẹ to wa nilẹ lori arun koronafairọọsi.
Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun tun ti sọ pe ki gbogbo igbesẹ to wa nilẹ lori ọrọ arun atakanlẹ nni koronafairọọsi ko si maa tẹsiwju fun ọsẹ meji mii in, kawọn tun to mo nnkan tawọn yoo ṣe.

Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Kunle Somorin, to jẹ akọwe iroyin fun Gomina naa fi sita lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, lo ti sọ pe ki konile- o- gbele to n waye lopin ọsẹ si tẹsiwaju ati awọn ile ijọsin gbogbo naa ṣi wa ni ọlude lati fi dena arun to tan kalẹ yii.

O fikun un pe awọn gbe igbesẹ naa latari ero inu awọn to kọṣẹ mọṣẹ lawujọ ti wọn sọ pe igbogun ti arun naa si n tẹsiwaju ati pe gbogbo ọna ni wọn n gba lati rii pe adinku de ba patapata, idi niyii to fi ni wọn ṣafikun ọsẹ meji ọhun

O sọ pe ipinlẹ Ogun yoo tubọ tẹsiwaju lati maa fikun-lun-kun, iwoye lati gbe igbesẹ to ga fun abo araalu lari rii pe korona fairọọsi yii kasẹ nilẹ patapata, ti ifọkanbalẹ yoo si wa pẹlu.
Dapọ Abiọdun ṣalaye pe titi di akoko yii, awọn ti wọn ti ṣayẹwo arun naa fun nipinlẹ Ogun ti le ni ẹgbẹrun mẹrin le ni mejilelaadọrin, nigba tawọn bi ẹgbẹrin le mejidinlaadọrun ti lu gbadi ẹ, lara awọn to lugbadi ẹ ni ẹẹdẹgbẹta le mẹsan-an ni wọn ti laṣeyọri ti ifọkanbalẹ wa pẹlu wọn, nigba ti mọkadilogun ti tipasẹ jẹ Ọlọrun  nipe.
O ni lara ibi ti aisan naa pọ si ti wọn ti ri wọn jẹ lara ijọba ibilẹ to mule ti ipinlẹ mii in lorileede yii. O ni awọn ṣafikun ọsẹ meji yii kawọn tun le tun forikori wa ọna abayọ.
Dapọ Abiọdun tun mẹnuba pe bijọba apapọ ṣe gbẹsẹ kuro lori irinna fawọn to ba n rin irinajo lati ipinlẹ kan si keji yoo jẹ erongba rere lati jẹ kawọn woye bi nnkan ba ṣe n lọ nipa aisan korona yii ati pe ko na wọn ni nnkakan lati ṣatunṣe lori ẹ.

No comments:

Post a Comment

Pages