Fawọn ti ko ti i gbagbọ pe arun to gbode bayii iyẹn koronafairọọsi ko si, ijọba n parọ ni, ki wọn ya tete mu iru ero ọkan bẹẹ kuro lọkan wọn,nitori bi arun naa ṣe n fojoojumọ gbilẹ si nipinlẹ Ogun.
Gbajumọ obinrin sọrọsọrọ ori redio nni, Ẹniọla Anikẹ
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lọsẹ to kọja ni obinrin naa lọ ṣe ayẹwo ara ẹ, nigba ti wọn sọ pe o fẹ rẹ ẹ diẹ, ṣugbọn abajade esi ayẹwo naa to jade lọsẹ yii lo fihan pe arun naa ti wa lara ẹ.
Ọpọ awọn to gbọ ọrọ naa ni wọn ko gbagbọ ti wọn si n sọ pe ahesọ lasan ni.Eyi lo mu ki oniroyin wa pe sọrọsọrọ ori redio naa, lati mọ boya ootọ ni, ṣugbọn a ko tii sọrọ delẹ nigba taa pe lori foonu, to ti sọ pe oun mọ nnkan ta pe oun fun, to si sọ pe loootọ loun ti lugbadi arun naa ati pe oun wa nile ifipamọ ti wọn n fawọn to ni iru nnkan bẹẹ si, toun gba itọju lọwọ
O wa lo akoko naa
lati sọ fawọn araalu ti wọn ko nigbagbọ pe loootọ ni arun naa wa, ki wọn si sọra fawọn nnkan to le dena
aisan yii, lati maa pa awọn ofin tijọba la kalẹ fun wọn mọ.
Bẹẹ lo wa mu dawọn oloolufẹ ẹ loju pe lagbara Ọlọrun ko
ni sewu lẹyin toun ba ti gba itọju tan, tara oun ya daadaa, oun yoo pada sori
eto oun nibi ti wọn yoo tun ti ma jẹ igbadun oun lọ.
No comments:
Post a Comment