Ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ti tẹ ayederu lọya kan, Ayọdeji Ojo, ẹni ti wọn fẹsun kan pe ti lu ọpọ awọn eeyan nijibiti owo nla lati fi bawọn ṣẹjọ.
Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe
wi, wọn ni lọya kan lo kọ lẹta ifẹsun kan si ọga ọlọpaa iyẹn DPO, to wa ni
Ajuwọn, pe o ti pẹ ti Ayọdeji ti n fi lọya lu awọn eeyan nijibiti, ti ko si n
ṣe ara awọn, to si n ba awọn niṣẹ jẹ.
Koda wọn sọ ninu iwe
ẹsun naa pe ọkunrin yii ko lọ sileewe ti wọn ti n kọ nipa ofin kankan depodepo
pe yoo di lọya, ayederu ni wọn pe, ki wọn bawọn ṣiṣẹ le e lori.
Iwe ẹsun yii la gbọ pe
awọn ọlọpaa ṣiṣẹ le lori labẹlẹ, ti aṣiri ẹ fi tu nigba to gba ẹgbẹrun lọna
ọọdunrun naira lọwọ obinrin kan tọwọ tẹ, to si foju bale ẹjọ ṣugbọn to ni oun
yoo fi gba beeli ẹ.
Wọn ko jẹ ko bọ mọ wọn lọwọ ti wọn fi mu, pẹlu awọn ẹri tawọn
ọlọpaa tun ni fi han pe loootọ lo lọ sileewe giga yunifasiti ni Ekiti, lati kọ ẹkọ naa ṣugbọn wọn ni ko kọ
pari to fi sa kuro nibẹ.
Kenneth Ebrimson,
kọmiṣanna awọn ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ti ni ki wọn mu afurasi ọhun wa si
Eleweran, ki iwadii tunbọ tẹsiwaju, ko to foju bale ẹjọ.
No comments:
Post a Comment