Adojutini Pasitọ kan ree; ọmọ ọdun mejila lo fipa ba lo pọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 3 July 2020

Adojutini Pasitọ kan ree; ọmọ ọdun mejila lo fipa ba lo pọ


 
Niyi Ọmọwoọdun, Pasitọ ijọ Helmet of Life International, to wa ni Ejigun Agbẹdẹ, Itẹle- Ọta, nijọba ibilẹ Ado-Odo nipinlẹ Ogun, tọwọ tẹ pe o fi tipa bọmọ ọdun mejila sun, ninu ile kan ti wọn ko tii kọ pari ti sọ pe oun ko mọ igba ti ẹmi agbere gbe oun wọ, toun fi huwa to wu naa. Ati pe bigba toun ba agbalagba sun lo ri.

Lakooko to n sọrọ ni teṣan awọn ọlọpaa to wa, o ni eṣu ti ya oun lo tan, koun to mọ pe nnkan toun ṣe naa ko dara, a fi ki Ọlọrun dari ji oun,nitori aṣiṣe nla lo jẹ foun.

Lọsẹ to kọja lọwọ tẹ Pasitọ, ẹni ọdun mẹrinlelaadọta ọhun, lẹyin ti Baba ọmọ naa ti lọ fẹjọ sun ni teṣan awọn ọlọpaa to wa ni Itẹle pe ib iṣẹ loun wa ti ọkan lara awọn alajọgbe oun pe oun lori foonu pe agbalagba kan fipa ba ọmọ oun sun.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, iṣẹ ni wọn ran ọmọ naa, ti Ọkunrin yii fi dọgbọn tan ọmọ naa wọ ile ti wọn ko tii kọ tan kan to wa lagbegbe ọhun to si ko ibasun fọmọ ọdun mejila yii.

Loju ẹsẹ ti Baba ọmọ yii ti lọ fẹjọ sun lawọn ọlọpaa ti gbe igbesẹ ti wọn si mu Pasitọ naa, nigba to si ti mọ pe aṣiri iwa ibi toun wu lu tu, ṣe lo ni kawọn ọlọpaa ma wahala ju, oun yoo jẹwọ fun wọn.

Bi wọn ṣi ṣe de teṣan lo ti bẹrẹ si ni ka pe lati nnkan bi ọdun mẹrin sẹyin loun ati iyawo oun ti pin ya. Ati pe lọjọ tiṣẹlẹ naa waye, oun ko le sọ bi ẹmi naa ṣe gbe oun wọ, toun fi tan ọmọ naa lọ sibi toun ti fi tipa ba sun.

Ni bayii, kọmiṣanna awọn ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Kenneth Ebrimson, ti paṣẹ pe ki wọn mu ọkunrin naa lọ si ẹka to n ri si lilo awọn ọmọ nilokulo, ki iwadii si tẹsiwaju.

Ṣugbọn o da oun loju pe Pasitọ naa yoo foju bale ẹjọ lati sọ jẹwọ ẹṣẹ ẹ fun Adajọ

No comments:

Post a Comment

Pages