Ọgbẹni Sunday Ọlapọsi Ọginni, to jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu New Nigeria People’s Party, NNPP, nipinlẹ Ogun ti sọ pe ko si saye fawọn jaguda ti wọn fẹ gbowo ilu, ti wọn fẹẹ jẹ gbese silẹ tabi ta ipinlẹ naa, nitori ẹgbẹ oṣelu wọn ko ni gba.
O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ, o ni ẹtọ ọmọ
ipinlẹ naa ni pe ki wọn pariwo pe awọn ko gba lati fi wọn yawo. Ko si owo ẹru mọ,
o ti to gẹ nipinlẹ naa.
O fikun ọrọ ẹ pe ẹdun ọkan lo jẹ nigba ti ẹyawo biliọnu
aadọta-le-nigba naira ti Ijọba Dapọ Abiọdun sọ pe awọn fẹẹ gba. O ni awọn ko sọ
pe kijọba ma sọ pe awọn fẹẹ lọ ya owo ṣugbọn o gbọdọ jẹ eyi to ni itumọ.
O ni owo eyi ti wọn sọ pe awọn fẹẹ ya yii ko nitumọ
nitori ẹ lawọn ṣe sọ pe awọn yoo lo ti ẹgbẹ tuntun toun ṣẹṣẹ di alaga yii lati
pariwo sita. Gbogbo agbara ati ipa lawọn yoo si sa lati ri pe wọn ko rowo naa
gba.
O sọ pe o da oun loju pe ẹgbẹ oṣelu oun iyẹn NNPP ni yoo
gbajọba ipinlẹ Ogun ninu ibo to n bọ, awọn ko si le ba gbese ti ko nitumọ nilẹ
tabi kawọn kan ko owo sa lọ, ki wọn wa da gbogbo araalu soko gbese.
Ọginni tun sọ pe awọn fẹẹ ki Dapọ Abiọdun mu ẹri jade wa
nibi toun atawọn igbimọ ti jọ pete pero lori owo ti wọn ya naa sita. O ni iyalẹnu
igbesẹ tawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin gbe lori ọrọ naa, to si tun jọ awọn eeyan loju.
O ni ko si nnkan to n jẹ ero araalu to yẹ kawọn ọmọ igbimọ
aṣofin ṣe lori owo naa, koda ki owo naa kere ju bẹẹ lọ. Ko si nnkan to n jẹ ifikunlukun,
nnkan tawọn kan gbọ ni pe wọn faṣẹ si yiya owo ọhun.
O ni ‘’Ko jẹ atẹwọgba gbogbo ọna la yoo si ba wọn faa. A
fẹẹ fi akoko yii kilọ fawọn ileeṣẹ nipa isuna lati yẹra fun wọn, Nitori ọna lati
ko wahala ọjọ iwaju ba ipinlẹ Ogun, awa ko si le gba, eyi ni igbesẹ ti wa lori ọrọ
yii’’
No comments:
Post a Comment