Wọn ti sin oku OgunMajek, ọga onitiata - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 26 June 2020

Wọn ti sin oku OgunMajek, ọga onitiata
 Lọjọbọ, Tọsidee, ana ni wọn sin oku agba oṣere onitiata nni, Alaaji Gbọlagade Akinpẹlu, tọpọ mọ si OgunMajek, ni ile wọn to wa ni aba Elesude, ni Ọmi-Adio, Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.

Bo tilẹ jẹ pe akoko taa wa yii fifofin de lilọ bibọ lati ipinlẹ kan si ikeji si n waye, eyi lo jẹ kọpọ awọn oṣere tiata ma le yọju sibi ayẹyẹ isinku sibẹ awọn oṣere tiata ti wọn wa ni Ibadan ṣoju ṣẹyin nibi ayẹyẹ to waye naa.

Laaarọ Ọjọbọ ana ni iku pa oju wọn de nile iwosan kan ti wọn ti n gba itọju lati nnkan bi oṣu meloo kan sẹyin. Igba kan tiẹ kọkọ wa ti gbe awọn ahesọ kan jade pe ọkunrin naa ti jade laye ṣugbọn ti ọrọ ko ri bẹẹ.

Agba ọjẹ ni Alaaji Gbọlagade Akinpẹlu nidii iṣẹ tiata, wọn ti wa lẹni iṣẹ naa yoo ti le ni ogoji ọdun. Ninu ere ọlọsẹ mẹtala kan ti wọn ṣe fun tẹlifisan TSOS to di BCOS nipinlẹ Ọyọ ni wọn ti ṣere kan ti akọlẹ ẹ n jẹ Lakaaye, nibẹ ni ọkunrin yii ti kopa to jọju to ṣe Ogun, idi niyii tọpọ eeyan fi maa n pe wọn ni Ogun titi di oni yii.

Bẹẹ naa lo ṣe jẹ pe ninu fiimu kan ti wọn ṣe, ti wọn jẹ Majọkodunmi, lo tubọ pologo okiki wọn nidii iṣẹ tiata, apapọ Ogun ati Majẹkodun lawọn eeyan sọ di OgunMajek ti wọn n pe wọn.


Bi Alaaji Gbọlọgade ṣe mọ nipa ere tọlifisan, fiimu bẹẹ lo tun mọ nipa ere ori itage, o fẹẹ jẹ pe nipa ere ori itage gan an ni wọn ti bẹrẹ nigba naa. Ọpọ awọn agba oṣere lọkunrin naa ti ba ṣiṣẹ pọ bi Alaaji Oloye Deji Aderemi, tẹpẹ mọ si Ọlọfaana, Musilu Dasọfunjo tọpọ mọ si Eṣu, Alaaji Kareem Ọlatinwọ tọpọ mọ si Tọwọndun, Mukaila Ariyọ, Kabiru Awodele, Tọla Oyedokun atawọn mii in ni ti wọn jẹ wa nigba naa.

Gbọlagade lẹgbẹ oṣere tiẹ to da silẹ lọtọ, ki wọn to jọ ṣiṣẹ pọ mọ ti Olofaana. Bakan  naa lo ti bi Ologbe Hubet Ogunde, Ologbe Mosses Olaiya, atawọn mii in kopa ninu fiimu wọn.


Ka ni iku ko pa oju ọkunrin naa de ni ọjọ kẹtala, oṣu kẹjọ, ni OgunMajek ko ba pe Aadọrin ọdun. Iyawo atawọn ọmọ lo fi silẹ saye lọ, Lara wọn ni Adeọla Akinpẹlu Adeọla akọbi ẹ lobinrin, Akimu Akinpẹlu, Kabira Akinpẹlu, Oyindamọla Aṣeyọri Akinpẹlu ataw

No comments:

Post a Comment

Pages