Sunday Ọlapọsi Ọginni, to ti figba kan jẹ akọwe fẹgbẹ oṣelu Lebọ nipinlẹ Ogun, to tun jẹ alaga fawọn apapọ ẹgbẹ oṣelu ti wọn forukọ silẹ, la gbọ pe o ti dagbere fẹgbẹ oṣere Lebọ bayii to si ti di alaga fẹgbẹ oṣelu New Nigeria People Party nipinlẹ naa.
Bo tilẹ je pe lakooko taa wa yii ni ajọdun fi fẹgbẹ oselu
kan silẹ bọ si omii in, eyi to ti waye nipinlẹ Edo ati Ondo, ni bayii ipinlẹ
Ogun ni igbesẹ yii ti waye to si sọ Ọginni di alaga ẹgbẹ oṣelu tuntun.
Nibi eto naa to waye niluu Abẹokuta, ni Ọgbẹni Babatunde Ọkẹ,
to jẹ igbakeji ẹgbẹ NNPP nilẹ Yoruba ti nawọ Sunday Ọginni soke pe ẹni tawọn mọ
pe ipo naa tọ si nipinlẹ Ogun niyii.
Ninu ọrọ Ọkẹ, o sọ pe pẹlu igbagbọ ati idaniloju oun da
oun loju pe lakooko ti Ọginni di alaga fẹgbẹ oṣelu naa, wọn yoo ni oludije ti
yoo fun ipo gomina atawọn ipo yooku ninu ibo to n bọ nipinlẹ Ogun.
O wa ni iṣẹ akọkọ to wa niwaju ẹ ni lati yan awọn ti yoo
baa ṣiṣẹ pọ ti yoo tan kaakiri ipinlẹ Ogun, ti wọn yoo jẹ ẹni to le fi tọkantọkan
ṣiṣẹ ti wọn ba gbe le wọn lọwọ.
O ni awọn akitiyan Ọginni nidi oṣelu lo jẹ ki wọn gbe ipo
tuntun naa fun un to si dawọn loju pe yoo ṣe e lọna tootọ ati eyi to yẹ lati mu
ilọsiwaju ba ẹgbẹ naa.
Ninu ọrọ alaga tuntun ọhun, Sunday Ọginni, dupẹ pupọ lọwọ
ẹgbẹ oṣelu NNPP lori bi wọn ṣe ro rere kan oun ati pe oun yoo mu dawọn loju pe ẹgbẹ
naa ko ni rẹyin rara.
O sọ pe ẹgbẹ naa
yoo bẹrẹ si nii rinlẹ lati akoko yii lọ ati pe awọn yoo ri pe awọn gbajọba lọdun
2023. O ni ẹgbẹ olounjẹ lẹgbẹ naa, nitori ebi n pa ọpọ awọn eeyan bayi.
O ni ‘’Bi ẹ ba wo ami idanimọ wa, ẹ o rii pe ounjẹ lo kun inu ẹ, akọkọ to ṣe pataki ni pe
ki ebi maa pa araalu. A ṣetan lati mu irọrun ba awọn eeyan, ipolongo si ti bẹrẹ’’
Lori ẹgbẹ oṣelu Lebọ to wa tẹlẹ, Ọkunrin naa sọ pe ‘’Ẹgbẹ
naa ẹgbẹ to dara ni, ṣugbọn awọn jaguda ti wọnu ẹgbẹ lebọ,lati oke de isalẹ, ẹnikan
to lorukọ gidi ninu wọn ni Bọde Simeon. Ohun to ṣẹlẹ ni pe ẹgbẹ tuntun yii,
gbogbo awọn eeyan tuntun, awọn oloselu tuntun, awọn oloṣelu atijọ, ti wọn n fẹ
ki nnkan tuntun ṣẹlẹ nipinlẹ Ogun, la jọ maa ṣe’’
No comments:
Post a Comment