Ẹgbẹ ADACI fawọn eeyan ilu Meiran lounjẹ lọfẹẹ layajọ ọjọ iranti awọn baba nla wọn. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 21 June 2020

Ẹgbẹ ADACI fawọn eeyan ilu Meiran lounjẹ lọfẹẹ layajọ ọjọ iranti awọn baba nla wọn.


  

Fun ti ayẹyẹ ọlọdọọdun ti wọn fi maa n ṣe iranti awọn baba nla wọn, ẹgbẹ kan ti wọn pe to maa n ṣe iranti ẹgbẹẹgbẹrun awọn adulawọ ti wọn ṣegbe sinu odo mẹditeriani, atawọn ti wọn ye lasiko iṣowo ẹru,iyẹn African Diaspora Ancestral Commemoration Institute, ADACI, ti ẹka orileede yii ṣabẹwo siluu Meiran nipinlẹ Eko, lọjọ Aiku Sannde, to koja, nibi ti wọn ti ṣayajọ ọjọ naa.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ṣe lawọn araalu naa tu yẹyẹ jade sita lati wa bawọn eeyan naa ṣajẹyọ tọdun yii. Ọba Samuel Awoyẹmi Oroja, Akarakiri Keji, Onimeran tiluu Meran, lo gba awọn ọmọ ẹgbẹ naa lalejo, to si  fẹmi imoore ẹ han lori bi wọn ṣe gbe ayẹyẹ ọhun wa silu ẹ.

Pẹlu ki ayajọ ọdun naa le dun, ẹgbẹ ADACI tun lo anfaani naa lati fawọn araalu naa lounjẹ fun iranlọwọ wọn lori aisan koronafairọọsi to wa nita yii, eyi to jẹ ki inu Ọba naa tun dun ladun ju.


Nigba ti Iyaafin Laide Gold, to jẹ aṣoju ADACI lorukọ Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Oloye Fakunle Oyesanya, sọ lo ti ṣapejuwe ẹgbẹ ADACI gẹgẹ bi eyi to yẹ ki gbogbo ọmọ ilẹ adulawọ darapọ mọ nitori yatọ si pe aṣa ati iṣe adulawọ wa ninu ẹ pupọ, o tun jẹ eyi taa le fi sunmo orisun wa daadaa.

Ninu ọrọ idupe  Kabiyesi, Ọba Meiran, ti sọ pe oun dupẹ lọwọ ADACI fun bi wọn ṣe nawọ iranwo ọhun. O ṣeleri pe ohun manigbagbe ni nnkan ti ẹgbẹ naa ṣe fawọn araalu oun, yoo si wa ninu itan titi lai.

Oba naa sọ pe ‘ Aṣiri ti ko bo ni pe ajakalẹ arun koronafairọọsi ti ṣakoba to pọ fun ọrọ aje lorileede yii, leyi to mu ki nnkan fa seyin diẹ, ti ọpọ ko si rọwọ mu lọ sẹnu, nitori naa iranwo ounjẹ ti ADACI ṣe lakooko yii  daa, bẹẹni awọn ti wọn jẹ anfaani rẹ ko nii gbagbe ẹgbẹ naa titi’’.

Bẹẹ lawọn ẹgbẹ Bọbakẹyẹ ilu Meiran naa dupe lowo ADACI, fun igbesẹ ẹyinju aanu ti wọn gbe, wọn ni nitori pe iru ẹ wọpọ lakooko yii.

ADACI, jẹ agekuru African Diaspora Ancestral Commemoration Institute, eyi ti wọn da silẹ lorileede Amerika, ni Washington DC, lọdun1992 , lati maa ṣe iranti ẹgbẹẹgbẹrun awon adulawo ti won segbe sinu odo mediteriani atawọn ti wọn ye lasiko iṣowo ẹru, ko sẹni ti ko le darapọ mọ ẹgbẹ yii, Oloye Fakunle Oyesanya ni Aarẹ ẹka ẹgbẹ naa ni Naijiria

No comments:

Post a Comment

Pages