Lati aarọ yii ni oriṣiriṣi orin ọkan-ọ-jọkan ti n waye
lati ba Gomina ẹgbẹ apapọ olorin nipinlẹ Ogun, Alaaji Saheed Akangbe Bọlọmọpe tọpọ
awọn eeyan mọ si Landoma ṣayẹyẹ ọjọọbi ẹ to n ṣe loni in.
Agba olorin fuji nni, Alaaji Sẹfiu Alao, tọpọ mọ si Baba
oko, lo ṣe ara ọtọ orin fun ọkunrin ọlọjọọbi, toun naa jẹ onifuji yii nibi to
ti baa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun bo ṣe daa si dọjọ oni.
Bẹẹ lo tun ṣapejuwe Landoma gẹgẹ ẹni to ni suuru, to si tẹriba
fun agba, atawọn aṣeyọri ẹ latigba to ti di alaga fun gbogbo awọn olorin nipinlẹ
naa, O wa ṣadura fun un pe ki Ọlọrun jẹ ko ṣọpọ ọdun laye.
Bakan naa ni Ere Asalatu, Leke Iyanda naa tun ṣe akanṣe
orin ranpẹ laye ọtọ fun Gomina wọn yii, tawọn si tun ba dupẹ pe ko sọpọ ọdun
laye, ti wọn lawọn si ba yọ pẹlu.
Landoma ti wa dupẹ lọwọ gbogbo awọn to n kii fun ti ayẹyẹ naa lati aarọ wa pẹlu adura pe oun ko ni tẹ lọwọ wọn
Landoma ti wa dupẹ lọwọ gbogbo awọn to n kii fun ti ayẹyẹ naa lati aarọ wa pẹlu adura pe oun ko ni tẹ lọwọ wọn
No comments:
Post a Comment