Bo tilẹ jẹ pe ero ọkan awọn araalu nipinlẹ Ogun, ni pe o ṣe
e ṣe ki Gomina ipinlẹ ọhun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun paṣẹ ṣiṣi ṣọọsi ati mọṣalaṣi gẹgẹ
bi ero ẹ nigba to bawọn oniroyin sọrọ gbẹyin, tọpọ wọn si ti n wa ni imurasilẹ ṣugbon
pabo lo ja si nigba to kede pe ki wọn si ti awọn ile ijọsin naa pa.
Ninu ipade to bawọn oniroyin ṣe nirọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee,
ọsẹ to kọja lo ti sọ pe pẹlu bi aisan korona ṣe tun n gbilẹ si yoo ṣoro fun
ijoba ipinlẹ Ogun, lati ṣi awọn ṣọọsi naa.
O sọ pe pẹlu awọn akọsilẹ tawọn ni, o ni awọn to tun ti
lugbadi aisan yii nipinlẹ Ogun, tun ti to idameji awọn to ti ni tẹlẹ lọ, bawọn
ko ba si gbe igbesẹ ki wọn ṣi ti awọn ile ijọsin pa, o ṣe e ṣe kawọn eeyan tun
tara ẹ lugbadi koronafairọọsi naa.
O fi kun ọrọ ẹ pe gbobo ilana tawọn la silẹ ni yoo maa tẹsiwaju
o, iyẹn ni pe aye yoo wa fawọn eeyan lati maa jade lati ọjọ Aje, Monde si ọjọ Ẹti,
Furaidee, nigba ti konile-o-gbele yoo wa lọjọ Abamẹta, Satide ati ọjọ Aiku,
Sannde.
Bẹẹ lo tun kilọ pe bi nnkan ṣe n lọ yii, o ṣe e ṣe ki wọn
fofinde awọn ọlọkada nipinlẹ naa bi wọn ba kọ lati maa pa ofin ati ilana tawọn
la kalẹ lati maa tẹle lori ọrọ koronafairọọsi yii.
Bakan naa lo ni ijọba ko ni foju rere wo awọn ile-iworan
ati igbafẹ ti wọn kọ eti ikun si ofin ijọba. Lilọ bibọ lati ipinlẹ kan si ikeji
to ni ijọba apapọ fofinde lo ni yoo tun maa tẹsiwaju ati iṣede laaarin aago
mewaa alẹ si mẹrin aarọ kutu naa ko yipada.
O wa sọ pẹlu idaniloju pe laipẹ yii ni aisan korona naa yoo
dohun itan nipinlẹ Ogun ati lorleede yii lapapọ.
No comments:
Post a Comment