Bẹẹ ni wọn yan Iyẹru gẹgẹ bi alaga olusakoso garaji
Agbẹjọro Sunday Adeniyi, to jẹ alaga
fun igbimọ to n ri si irinna ọkọ nipinlẹ Ogun ti sọ di mi mọ yiyan Alaaji Akeem
Bọdunrin, tọpọ mọ si Iyẹru gẹgẹ bi alaga ti yoo maa ṣakoso garaji iyẹn Park
Management
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n
kopa lori eto redio Sweet 107.1FM, O ni
ijọba ipinlẹ Ogun, ti fofinde gbogbo lilọ bibọ ẹgbẹ awakọ naa lati akoko yii lọ.
O ni igbesẹ yii
waye nitori wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ ọhun. O ni ijọba ti gbe awọn igbesẹ kan
lati le jẹ ki awuyewuye naa dopin.
Agbẹjọro Sunday Adeniyi tun ṣalaye
siwaju pe" Ijọba ipinlẹ Ogun ti yan Alaaji Akeem Abodunrin Iyeru gẹgẹ bi alaga ti yoo maa ṣakoso awọn garaji.
Oun ni wọn sọ pe yoo maa gbowo lọsẹ awọn awakọ NURTW nipinlẹ Ogun.
"Gbogbo agbara ni isakoso ijọba
Dapọ Abiọdun, yoo ma sa lati ri pe abo to peye wa fun awọn olugbe ipinlẹ naa,
to fi mọ awọn dukia wọn pẹlu nipinlẹ Ogun’’
O fikun ọrọ ẹ pe titi di akoko yii
nipinlẹ Ogun, ko si nnkan to n jẹ ẹgbẹ awakọ ati pe wọn ti fofin de wọn titi ti
wọn yoo fi yanju aawọ to wa laarin wọn.
O ni ẹnikẹni ti
ẹgbẹ awakọ NURTW ba n wu ṣe, ko lọ darapọ mọ wọn lawọn ipinlẹ to sunmọ ipinlẹ
Ogun. O ni Alaaji Iyẹru ni yoo jẹ olori ti yoo maa gbowo lọwọ awọn onimọto
lakooko ọsẹ awọn awakọ NURTW.
Agbẹjọro Sunday Adeniyi, wa fi kun
ọrọ ẹ pe ẹnikẹni to ba pe ara ẹ lọmọ ẹgbẹ awakọ NURTW yoo foju winna ofin
ijọba.
Bakan naa ni agbẹnusọ awọn ọlọpaa
nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, naa sọ lọjọ Aje, Monde, pe awọn ko gbọ nnkankan
boya ibo ti Alaaji Tajudeen Baruwa, ṣaaju ẹgbẹ naa lapapọ waye, o wa ṣeleri pe
gbogbo ọna lawọn yoo sa lati ma ṣe jẹ kawọn kan da wahala silẹ nipinlẹ naa.
|
||
No comments:
Post a Comment