Iyaafin Oluwafunmilayọ Irede Ọginni, to jẹ igbakeji akọwe ẹgbẹ oṣelu PDP ti igun Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu, ti rọ awọn agba ẹgbẹ naa lati ba Sẹnetọ Buruji Kashamu sọrọ, ko ye ta ẹgbẹ naa fawọn alatako mọ.
O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa fọrọjomitoro ọrọ,
O ni oun mọ pe Sẹnetọ Buruji Kashamu, ọmọ ẹgbẹ PDP ni wọn, ṣugbọn o n ta ẹgbẹ naa
fawọn alatako awọn ni.
Ṣugbọn o da oun loju pe pẹlu ibi tawọn ba atunto ẹgbẹ naa
de lagbara Ọlọrun, ki ọdun yii to pari, PDP ipinlẹ Ogun yoo fẹsẹmulẹ. To si da
oun loju pe Ọnarebu Ladi Adebutu ni yoo jẹ gomina lọdun 2023.
Irede tun sọ pe ‘’Ko si nnkan ti Ọlọrun ko le ṣe, nitori ọkan
wa n bẹ lọwọ Ọlọrun, ọkan ijoye naa n bẹ lọwọ rẹ pẹlu, ti Ọlọrun ba ṣetan lati mu ọkan Buruji, Ọlọrun a gba a to fi jẹ pe ẹgbẹ
naa yoo fẹsẹrinlẹ.’’
‘’Ẹgbẹ onigbalẹ to
n ṣejọba ko si nnkan ti wọn ṣe faraalu, wọn si ti n wa ẹgbẹ ti yoo fẹsẹrinlẹ,
ti yoo ṣe nnkan ti wọn ba n fẹ, nitori ko ti si nnkan ti wọn yoo sọ pe awọn ṣe
fun wa nigba to ba di ọdun 2023’’.
‘’A ti n sọ fawọn
agbaagba ẹgbẹ pe ki wọn ba Buruji sọrọ, ko ma fọwọ ẹgbẹ yii sẹyin. Ki isọkan ko
le wa, nitori inu awọn araalu ko dun si nnkan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ wa. Wọn ti dọkọ
ile meji wo, wọn ti mọ eyi to dara’’.
Nigba to n sọrọ
nipa ọdun kọkanlelogun ijọba tiwa-n-tiwa lorileede yii, obinrin naa sọ pe ‘’A
ko tii de ibi to yẹ ka de ninu ijọba tiwa-n-tiwa iyẹn dẹmokireesi, nitori latigba
ti Oloye MKO Abiọla ti ku, awọn nnkan yẹn si n ba jẹ si ni’’.
‘’Ko si atunṣe kankan nibẹ, ki Ọlọrun ranti gbogbo awọn aṣaaju
wa, ki wọn le ṣe nnkan to dara fun wa, wọn ni ọdọ ni ogo orileede, awa ko ri ọdọ
kankan ko ṣe ogo kankan.’
O ni nnkan toun ro pe a le ṣe ni pe akọkọ, ki a kọkọ bẹ Ọlọrun ko
le ran wa lọwọ, o ni a ti gbiyanju titi pe ki awọn to jẹ ọdọ ko le bọ siwaju, ki
ifọwọsowọpọ wa pẹlu awọn olori wa, ki wọn
le ṣe nnkan to tọ saarin ilu.
Ṣugbọn o ni iyalẹnu lo jẹ pe awọn agba ko fawọn ọdọ laye
lati sa ipa wọn, o ni a si n fẹ imọ Ọlọrun
lati jẹ ka de ibi taa fẹẹ de, awọn agba ko fẹẹ kawọn majesin de ibi ogo wọn. Ìṣẹ́
ti mu awọn ọdọ lẹwu lati ma jẹ ki wọn de ibi ti wọn fẹẹ de.
No comments:
Post a Comment