Ẹgbẹ apapọ awọn oloṣelu ti wọn forukọ silẹ nipinlẹ Ogun, eyi ti
Ọginni Ọlapọsi Sunday, jẹ aṣaaju fun, ti rọ Gomina Dapọ Abiọdun, lati ma ṣe jẹ ki
igbagbọ tawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ni ninu ẹ ja kulẹ lori bi wọn ṣe fọwọ si
ẹyawo aadọta-le nigba biliọnu naira tijọba ẹ bẹbẹ fun.
Ninu atẹjade kan ti Ọginni fi sita fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta,
Satide, lo ti gba ijọba Abiọdun nimọran lati lo owo naa lọna tootọ,ati eyi to yẹ, bi wọn ṣe la kalẹ pe awọn fẹẹ lo. O ni ki
akọsilẹ wa lori bi wọn ṣe n na owo ọhun
Bẹẹ lo tun rọ ọ lati ṣewadi lori bi wọn ṣe pin awọn ẹbun ounjẹ
ti wọn gba lakooko ti korona fairọọsi nipinlẹ yii.
Alaga naa tun ṣalaye siwaju pe awọn gboriyin fun bawọn ọmọ ile igbimọ
aṣofin, eyi ti Ọnarebu Kunle Oluọmọ jẹ olori fun bi wọn ṣe fọwọsi ẹyawo naa, ọkan
lara mimu idagbasoke ba ipinlẹ Ogun lo pe e.
O ni“ Ọkan wa ko balẹ lori taa si n woye nipa akosilẹ isiro
ijọba Dapọ Abiọdun. Akọsilẹ nipa isuna lori bi wọn ṣe pin awọn ẹbun fun ti
korona fairọọsi si mu ikunsinu wa tawọn araalu si fẹ mọ pato lori awọn nnkan
wọnyii’’.
Bẹẹ ni awọn apapọ ẹgbẹ
oṣelu naa tun rọ ijọba lati ri pe wọn pari awọn akanṣe iṣẹ tijọba to ko gba
wọle, o pari, niwọgba to jẹ pe isakoso ijọba n tẹsiwaju ni. Wọn tun ni ki wọn je
kawọn iṣẹ akanṣe idagbasoke jẹ eyi ti yoo kaakiri awọn igun mẹtẹẹta to wa
nipinlẹ Ogun.
Ọginni tun sọ pe“ Ni ipari, a rọ awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin
ipinlẹ Ogun, ki wọn ri pe wọn n ṣiṣẹ wọn lati ri pe gbogbo wọn ni wọn jẹ
anfaani ẹyawo ọhun lati fi mu idagbasoke ba agbegbe ti wọn ti wa’’.
Ọginni sọ pe pẹlu akọsilẹ to wa nilẹ, ko ti si gomina ninu awọn
to ti sejọba nipinlẹ Ogun, ti wọn gba iru ẹyawo owo eyi ti Dapọ
Abiọdun gba. O wa ni
awọn fẹẹ kojọba maa gbe bi wọn ṣe n nawo jade loṣoosu ninu awọn iwe iroyin, o
kere ju iwe iroyin mẹta lati ileeṣẹ eto isuna
|
No comments:
Post a Comment