Bi PDP yoo ṣe gbajọba ipinlẹ Ogun lọdun 2023, lo jẹ mi logun- Bamgboṣe - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 10 June 2020

Bi PDP yoo ṣe gbajọba ipinlẹ Ogun lọdun 2023, lo jẹ mi logun- BamgboṣeBamgboṣe Samson Olukayọde, to jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun, ti sọ pe nnkan akọkọ to wa niwaju oun bayii ni bi ẹgbẹ naa yoo ṣe gbajọba lọdun 2023, igbesẹ ẹ loun ti bẹrẹ bayii to si da oun loju pe yoo ṣe e ṣe lagbara Ọlọrun.

O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ ni ọfiisi ẹgbẹ naa to wa niluu Abẹokuta. O sọ pe latigba ti wọn ti ṣebura foun loun ti n ṣiṣẹ lati le ri pe isọkan pada sinu ẹgbẹ yii ati pe gbogbo awọn ti wọn ni ikunsinu kan sikeji lawọn ti n ba sọrọ ti idaniloju si wa pe didun ni ọṣan yoo so.

O ni nnkan tawọn kọkọ ri ni pe awọn gbọdọ wa ni ọkan ṣoṣo gẹgẹ bo ṣe wa tẹlẹ nigba aye Gbenga Daniel, o lawọn agbalagba ẹgbẹ ti wọn ṣiṣẹ naa lakooko yẹn, awọn ke gbajare lọ ba wọn.

O ni ọpọ awọn agba ẹgbẹ yii ni wọn kan sara sawọn pe inu awọn dun si igbesẹ tawọn n gbe yii pẹlu ileri pe awọn ṣetan lati ba wa ṣe ẹgbẹ PDP pada.
Lori wahala to ti wa ninu ẹgbẹ naa tẹlẹ lati nnkan bi ọdun mẹwaa sẹyin, 

Bamgboṣe sọ pe PDP to ṣẹṣẹ wa yii ki i ṣe atọwọda, bi Oluwa ti fẹ ni, o ni wahala to n ṣẹlẹ naa ki i ṣe irọ,ko si ẹgbẹ oṣelu tiru ẹ ki i ti waye,eti to da oun loju ni pe ki ọdun yii to pari gbogbo ẹ a lọ silẹ.

O ni ko sigba ta ajọ INEC ba fẹẹ gbe orukọ jade, wọn ki i gbe meji jade ninu ẹgbẹ wọn ẹyọ kan naa ni, ọkan lawọn, ati pe idaniloju wa pe eyi tawọn n lọ yii, awọn fẹẹ gbajọb ba lọwọ APC ni.

Bamgboṣe tun sọ pe oun ko le sọ nnkankan mọ lori bawọn ṣe de ipo eyi ti wọn lo n da awuyewuye silẹ nitori ọrọ to ba ti wa nile ẹjọ, o ti di tile ẹjọ, awọn ni yoo si mọ ibi ti wọn yoo da si.

Nigba awuyewuye to n ṣẹlẹ laaarin Buruji Kashamu ati Bayọ Dayọ to jẹ alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ, alaga ẹgbẹ PDP sọ pe oun ko le da si, bo tilẹ jẹ pe ko si nnkan to wa nile aye yii ti ko ni atunṣe.

O ni awọn mejeeji yii jọ wa pọ nigba kan, ṣugbọn owe kan sọ pe ẹpọn tẹpọn, awọ kan yi ju kan lọ, a ju ara wa lọ,ijakadi kọ, ọrọ ti wọn yẹn, to ba ri ba kan, wọn yoo mọ bi wọn yoo ṣe yanju ẹ.

O tun fikun pe awọn ti Adebutu ti ṣetan pọ lati ṣiṣẹ pọ pẹlu wọn ati pe ninu wọn a ti bawọn sọrọ lonii, o ni ọkọọkan lọmọ ọwọ yọ, ẹni to jẹ adari wọn Ogun West, awọn pade ni Ilaro, bo ṣi ṣe ri oun, lo wa ba oun to pe oun ni alaga.

O ni o da oun loju pe wọn yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu wọn tawọn yoo si jọ gbajọba lọwọ APC lọdun 2023.
No comments:

Post a Comment

Pages